Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 15:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá wí fún baba tàbí ìyá rẹ̀ pé, “Ẹ̀bun fún Ọlọ́run i ohunkóhun tí ìwọ ìbá fi jèrè lára mi;”

6. tí Òun kò sì bọ̀wọ̀ fún baba tàbí ìyá rẹ̀,’ ó bọ́; bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin sọ ofin di asan nípa àṣà yín.

7. Ẹ̀yin àgàbàgebè, ní òtítọ́ ni Wòlíì Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa yín wí pé:

8. “ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń fi ẹnu lásán bu ọlá fún mi,ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà réré sí mi.

Ka pipe ipin Mátíù 15