Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 15:33-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

33. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì dá a lóhùn pé, “Níbo ni àwa yóò ti rí oúnjẹ ní ihà níhìn-ín yìí láti fi bọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn yìí?”

34. Jésù sì béèrè pé, “ìsù Búrẹ́dì mélòó ni ẹ̀yín ní?”Wọ́n sì dáhùn pé, “Àwa ní ìsù àkàrà méje pẹ̀lú àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀.”

35. Jésù sì sọ fún gbogbo ènìyàn kí wọn jókòó lórí ilẹ̀.

36. Òun sì mú ìsù àkàrà méje náà àti ẹja náà. Ó sì fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run, ó bù wọ́n sì wẹ́wẹ́, ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n sì pín in fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn náà.

37. Gbogbo wọn jẹ, wọ́n sì yó. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì sa èyí tókù, ẹ̀kún agbọ̀n méje ni èyí tó sẹ́kù jẹ́

38. Gbogbo wọn sì jẹ́ ẹgbàají: (4000) ọkùnrin láì kan àwọn obìnrin àti ọmọdé.

39. Lẹ́yìn náà, Jésù rán àwọn ènìyàn náà lọ sí ilé wọn, ó sì bọ́ sínú ọkọ̀, ó ré kọjá sí Mágádánì.

Ka pipe ipin Mátíù 15