Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 15:13-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Jésù dá wọn lóhùn pé, “Gbogbo igi tí Baba mi ti ń bẹ ni ọ̀run kò bá gbìn ni á ó fà tu ti gbòǹgbò ti gbòǹgbò,

14. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀; afọ́jú tí ń fi ọ̀nà han afọ́jú ni wọ́n. Bí afọ́jú bá sì ń fi ọ̀nà han afọ́jú, àwọn méjèèjì ni yóò jìn sí kòtò.”

15. Pétérù wí, “Ṣe àlàyé òwe yìí fún wa.”

16. Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èé ha ṣe tí ìwọ fi jẹ́ aláìmòye síbẹ̀”?

17. “Ìwọ kò mọ̀ pé ohunkóhun tí ó gba ẹnu wọlé, yóò gba ti ọ̀nà oúnjẹ lọ, a yóò sì yà á jáde?

18. Ṣùgbọ́n ohun tí a ń sọ jáde láti ẹnu, inú ọkàn ni ó ti ń wá, èyí sì ni ó ń sọ ènìyàn di ‘aláìmọ́.’

19. Ṣùgbọ́n láti ọkàn ni èrò búburú ti wá, bí ìpanìyàn, panṣágà, àgbèrè, olè jíjà, irọ́ àti ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́.

20. Àwọn tí a dárúkọ wọ̀nyí ni ó ń sọ ènìyàn di ‘aláìmọ́.’ Ṣùgbọ́n láti jẹun láì wẹ ọwọ́, kò lè sọ ènìyàn di ‘aláìmọ́.’ ”

21. Jésù sì ti ibẹ̀ kúrò lọ sí Tírè àti Sídónì.

22. Obìnrin kan láti Kénánì, tí ó ń gbé ibẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ó ń bẹ̀bẹ̀, ó sì kígbe pé, “Olúwa, ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún mi; ọmọbìnrin mi ní ẹ̀mí èṣù ti ń dá a lóró gidigidi.”

23. Ṣùgbọ́n Jésù kò fún un ní ìdáhùn, Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á nìyànjú pé, “lé obìnrin náà lọ, nítorí ó ń kígbe tọ̀ wá lẹ́yìn.”

24. Ó dáhùn pé, “Àgùntàn ilẹ̀ Ísírẹ́lì tí ó nù nìkan ni a rán mi sí”

25. Obìnrin náà wá, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bẹ̀bẹ̀ sí i pé, “Olúwa ṣàánú fún mi.”

26. Ó sì dáhùn wí pé, “Kò tọ́ kí a gbé oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá.”

Ka pipe ipin Mátíù 15