Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 15:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ní àwọn Farisí àti àwọn olùkọ́ òfin tọ Jésù wá láti Jerúsálémù,

2. wọn béèrè pé, “Èé se tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ fi ń ṣe àìgbọ́ràn sí àwọn àṣà àtayébáyé Júù? Nítorí tí wọn kò wẹ ọwọ́ wọn kí wọ́n tó jẹun!”

3. Jésù sì dá wọn lóhùn pé, “È é ha ṣe tí ẹ̀yin fi rú òfin Ọlọ́run, nítorí àṣà yín?

4. Nítorí Ọlọ́run wí pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún Baba òun ìyá rẹ,’ àtipé, ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ òdì sí baba tàbí ìyá rẹ̀, ní láti kú.

Ka pipe ipin Mátíù 15