Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 15:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ní àwọn Farisí àti àwọn olùkọ́ òfin tọ Jésù wá láti Jerúsálémù,

2. wọn béèrè pé, “Èé se tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ fi ń ṣe àìgbọ́ràn sí àwọn àṣà àtayébáyé Júù? Nítorí tí wọn kò wẹ ọwọ́ wọn kí wọ́n tó jẹun!”

3. Jésù sì dá wọn lóhùn pé, “È é ha ṣe tí ẹ̀yin fi rú òfin Ọlọ́run, nítorí àṣà yín?

4. Nítorí Ọlọ́run wí pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún Baba òun ìyá rẹ,’ àtipé, ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ òdì sí baba tàbí ìyá rẹ̀, ní láti kú.

5. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá wí fún baba tàbí ìyá rẹ̀ pé, “Ẹ̀bun fún Ọlọ́run i ohunkóhun tí ìwọ ìbá fi jèrè lára mi;”

6. tí Òun kò sì bọ̀wọ̀ fún baba tàbí ìyá rẹ̀,’ ó bọ́; bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin sọ ofin di asan nípa àṣà yín.

7. Ẹ̀yin àgàbàgebè, ní òtítọ́ ni Wòlíì Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa yín wí pé:

8. “ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń fi ẹnu lásán bu ọlá fún mi,ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà réré sí mi.

9. Lásán ni ìsìn wọn;nítorí pé wọ́n ń fi òfin ènìyan kọ́ ni ní ẹ̀kọ́.’ ”

10. Jésù pe ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, ó wí pé, “Ẹ tẹ́tí, ẹ sì jẹ́ kí nǹkan tí mo sọ yé yín.

11. Ènìyàn kò di ‘aláìmọ́’ nípa ohun tí ó wọ ẹnu ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti ẹnu jáde wá ni ó sọ ni di ‘aláìmọ́.’ ”

Ka pipe ipin Mátíù 15