2. ó wí fún àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Dájúdájú Jòhánù onítẹ́bọmi ni èyí, ó jíǹde kúrò nínú òkú. Ìdí nìyí tí ó fi ní agbára láti ṣiṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí.”
3. Nísìnsin yìí Hẹ́rọ́dù ti mú Jòhánù, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì fi sínú túbú, nítorí Hẹ́rọ́díà aya Fílípì arákùnrin rẹ̀,
4. nítorí Jòhánù onítẹ̀bọmi ti sọ fún Hẹ́rọ́dù pé, “Kò yẹ fún ọ láti fẹ́ obìnrin náà.”
5. Hẹ́rọ́dù fẹ pa Jòhánù, ṣùgbọ́n ó bẹ̀rù àwọn ènìyàn nítorí gbogbo ènìyàn gbàgbọ́ pé wòlíì ni.
6. Ní ọjọ́ àsè ìrántí ọjọ́ ìbí Hẹ́rọ́dù, ọmọ Hẹ́rọ́díà obìnrin jó dáadáa, ó sì tẹ́ Hẹ́rọ́dù lọ́run gidigidi.
7. Nítorí náà, Hẹ́rọ́dù jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti fún un ní ohunkóhun ti ó bá béèrè fún.
8. Pẹ̀lú ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ó béèrè pé, “Fún mi ni orí Jòhánù onítẹ̀bọmi nínú àwo pọ̀kọ́”.