Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 13:52-58 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

52. Ó wí fún wọn pé, “Nítorí náà ni olúkúlùkù olùkọ́ òfin tí a ti kọ́ nípa ìjọba ọ̀run ṣe dàbí ọkùnrin kan tí í ṣe baálé ilé, tí ó mú ìṣúra tuntun àti èyí tí ó ti gbó jáde láti inú yàrá ìṣúra rẹ̀.”

53. Lẹ́yìn ti Jésù ti parí òwe wọ̀nyí, ó ti ibẹ̀ kúrò lọ.

54. Ó wá sí ìlú òun tìkára rẹ̀, níbẹ̀ ni ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn nínú Ṣínágọ́gù, ẹnu sì yà wọ́n. Wọ́n béèrè pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí ti mú ọgbọ́n yìí àti iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí wá?

55. Kì í há ṣe ọmọ gbẹ́nàgbẹ́nà ni èyí bí? Ìyá rẹ̀ há kọ́ ni à ń pè ní Màríà bí? Arákùnrin rẹ̀ ha kọ́ ni Jémísì, Jósẹ́fù, Símonì àti Júdásì bí?

56. Àwọn arábìnrin rẹ̀ gbogbo ha kọ́ ni ó ń bá wa gbé níhìn-ín yìí, nígbà náà níbo ni ọkùnrin yìí ti rí àwọn nǹkan wọ̀nyí?”

57. Inú bí wọn sí i.Ṣùgbọ́n Jésù wí fún wọn pé, “Wòlíì a máa lọ́lá ní ibòmíràn, àfi ní ilé ara rẹ̀ àti ní ìlú ara rẹ̀ nìkan ni wòlíì kò ti lọ́lá.”

58. Nítorí náà kò se iṣẹ́ ìyanu kankan níbẹ̀, nítorí àìnígbàgbọ́ wọn.

Ka pipe ipin Mátíù 13