Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 13:45-54 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

45. “Bákan náà ni ìjọba ọ̀run dàbí oníṣòwò kan tí ó ń wá òkúta olówó iyebíye láti rà.

46. Nígbà tí ó rí ọ̀kan tí ó ni iye lórí, ó lọ láti ta gbogbo ohun ìní rẹ̀ láti le rà á.

47. “Bákan náà, a sì tún lè fi ìjọba ọ̀run wé àwọ̀n kan tí a jù sínú odò, ó sì kó onírúurú ẹja.

48. Nígbà tí àwọ̀n náà sì kún, àwọn apẹja fà á sókè sí etí bèbè òkun, wọ́n jókòó, wọ́n sì ṣa àwọn èyí tí ó dára sínú apẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n da àwọn tí kò dára nù.

49. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí ní ìgbẹ̀yìn ayé. Àwọn ańgẹ́lì yóò wá láti ya àwọn ènìyàn búburú kúrò lára àwọn olódodo,

50. Wọn ó sì ju àwọn ènìyàn búburú sínú iná ìléru náà, ní ibi ti ẹkún àti ìpayínkeke yóò gbé wà.”

51. Jésù bí wọn léèrè pé, “Ǹjẹ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí yé yín.”Wọ́n dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ó yé wa.”

52. Ó wí fún wọn pé, “Nítorí náà ni olúkúlùkù olùkọ́ òfin tí a ti kọ́ nípa ìjọba ọ̀run ṣe dàbí ọkùnrin kan tí í ṣe baálé ilé, tí ó mú ìṣúra tuntun àti èyí tí ó ti gbó jáde láti inú yàrá ìṣúra rẹ̀.”

53. Lẹ́yìn ti Jésù ti parí òwe wọ̀nyí, ó ti ibẹ̀ kúrò lọ.

54. Ó wá sí ìlú òun tìkára rẹ̀, níbẹ̀ ni ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn nínú Ṣínágọ́gù, ẹnu sì yà wọ́n. Wọ́n béèrè pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí ti mú ọgbọ́n yìí àti iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí wá?

Ka pipe ipin Mátíù 13