Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 13:39-53 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

39. ọ̀tá tí ó gbin àwọn èpò sáàrin àlìkámà ni èṣù. Ìkórè ni òpin ayé, àwọn olùkórè sì ní àwọn ańgẹ́lì.

40. “Gẹ́gẹ́ bí a ti kó èpò jọ, tí a sì sun ún nínú iná, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí ní ìgbẹ̀yìn ayé.

41. Ọmọ Ènìyàn yóò ran àwọn ańgẹ́lì rẹ̀, wọn yóò sì kó gbogbo ohun tó ń mú ni dẹ́sẹ̀ kúrò ní ìjọba rẹ̀ àti gbogbo ènìyàn búburú.

42. Wọn yóò sì sọ wọ́n sí inú iná ìléru, níbi ti ẹkún òun ìpayínkeke yóò gbé wà.

43. Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò máa ràn bí òòrùn ní ìjọba Baba wọn. Ẹni tí ó bá létí, jẹ́ kí ó gbọ́.

44. “Ìjọba ọ̀run sì dàbí ìṣúra kan tí a fi pamọ́ sínú oko. Nígbà tí ọkùnrin kan rí i ó tún fi í pamọ́. Nítorí ayọ̀ rẹ̀, ó ta gbogbo ohun ìní rẹ̀, ó ra oko náà.

45. “Bákan náà ni ìjọba ọ̀run dàbí oníṣòwò kan tí ó ń wá òkúta olówó iyebíye láti rà.

46. Nígbà tí ó rí ọ̀kan tí ó ni iye lórí, ó lọ láti ta gbogbo ohun ìní rẹ̀ láti le rà á.

47. “Bákan náà, a sì tún lè fi ìjọba ọ̀run wé àwọ̀n kan tí a jù sínú odò, ó sì kó onírúurú ẹja.

48. Nígbà tí àwọ̀n náà sì kún, àwọn apẹja fà á sókè sí etí bèbè òkun, wọ́n jókòó, wọ́n sì ṣa àwọn èyí tí ó dára sínú apẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n da àwọn tí kò dára nù.

49. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí ní ìgbẹ̀yìn ayé. Àwọn ańgẹ́lì yóò wá láti ya àwọn ènìyàn búburú kúrò lára àwọn olódodo,

50. Wọn ó sì ju àwọn ènìyàn búburú sínú iná ìléru náà, ní ibi ti ẹkún àti ìpayínkeke yóò gbé wà.”

51. Jésù bí wọn léèrè pé, “Ǹjẹ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí yé yín.”Wọ́n dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ó yé wa.”

52. Ó wí fún wọn pé, “Nítorí náà ni olúkúlùkù olùkọ́ òfin tí a ti kọ́ nípa ìjọba ọ̀run ṣe dàbí ọkùnrin kan tí í ṣe baálé ilé, tí ó mú ìṣúra tuntun àti èyí tí ó ti gbó jáde láti inú yàrá ìṣúra rẹ̀.”

53. Lẹ́yìn ti Jésù ti parí òwe wọ̀nyí, ó ti ibẹ̀ kúrò lọ.

Ka pipe ipin Mátíù 13