31. Jésù tún pa òwe mìíràn fún wọn: “Ìjọba ọ̀run dàbí èso hóró músítádì, èyí tí ọkùnrin kan mú tí ó gbìn sínú oko rẹ̀.
32. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ èso tí ó kéré púpọ̀ láàrin èṣo rẹ̀, ṣíbẹ̀ ó wá di ohun ọ̀gbìn tí ó tóbi jọjọ. Ó sì wá di igi tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì wá, wọ́n sì fi ẹ̀ka rẹ ṣe ìbùgbé.”
33. Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn: “Ìjọba ọ̀run dàbí yíìsìtì tí obìnrin kan mú tí ó pò mọ́ ìyẹ̀fun (ìyẹ̀fun) púpọ̀ títí tí gbogbo rẹ fi di wíwú.”
34. Òwe ni Jésù fi sọ nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn, òwe ni ó fi bá wọn sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tó sọ.
35. Kí ọ̀rọ̀ tí a ti ẹnu àwọn wòlíì sọ lé wá sí ìmúsẹ pé:“Èmi yóò ya ẹnu mi láti fi òwe sọ̀rọ̀.Èmi yóò sọ àwọn ohun tí ó farasin láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá.”
36. Lẹ́yìn náà ó sì fi ọ̀pọ̀ ènìyàn sílẹ̀ lóde, ó wọ ilé lọ. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn wí pé, “Ṣàlàyé òwe èpò inú oko fún wa”.
37. Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ọmọ ènìyàn ni ẹni tí ó ń fúnrúgbìn rere.
38. Ayé ni oko náà; irúgbìn rere ni àwọn ènìyàn ti ìjọba ọ̀run. Èpò ni àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ ti èṣù,
39. ọ̀tá tí ó gbin àwọn èpò sáàrin àlìkámà ni èṣù. Ìkórè ni òpin ayé, àwọn olùkórè sì ní àwọn ańgẹ́lì.
40. “Gẹ́gẹ́ bí a ti kó èpò jọ, tí a sì sun ún nínú iná, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí ní ìgbẹ̀yìn ayé.
41. Ọmọ Ènìyàn yóò ran àwọn ańgẹ́lì rẹ̀, wọn yóò sì kó gbogbo ohun tó ń mú ni dẹ́sẹ̀ kúrò ní ìjọba rẹ̀ àti gbogbo ènìyàn búburú.