Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 13:23-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gba irúgbìn tí ó bọ́ sí orí ilẹ̀ rere ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó sì yé e; òun sì so èṣo òmíràn ọgọ́rọ̀ọ̀rùn, òmíràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n.”

24. Jésù tún pa òwe mìíràn fún wọn: “Ìjọba ọ̀run dàbí àgbẹ̀ kan tí ó gbin irúgbìn rere sí oko rẹ̀;

25. Ṣùgbọ́n ní òru ọjọ́ kan, nígbà tí ó sùn, ọ̀ta rẹ̀ wá sí oko náà ó sì gbin èpò sáàrin àlìkámà, ó sì bá tirẹ̀ lọ.

26. Nígbà tí àlíkámà náà bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà, tí ó sì so èso, nígbà náà ni èpò náà fi ara hàn.

27. “Àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ àgbẹ̀ náà wá, wọ́n sọ fún un pé, ‘Ọ̀gá, irúgbìn rere kọ́ ni ìwọ ha gbìn sí oko rẹ nì? Báwo ni èpò ṣe wà níbẹ̀ nígbà náà?’

28. “Ó sọ fún wọn pé, ‘Ọ̀tá ni ó ṣe èyí.’“Wọ́n tún bí i pé, ‘Ǹjẹ́ ìwọ ha fẹ́ kí a tu èpò náà kúrò?’

29. “Ó dá wọn lóhùn pé, ‘Rárá, nítorí bí ẹ̀yin bá ń tu èpò kúrò, ẹ ó tu àlìkámà dànù pẹ̀lú rẹ̀.

30. Ẹ jẹ́ kí àwọn méjèèjì máa dàgbà pọ̀, títí di àsìkò ìkórè. Èmi yóò sọ fún àwọn olùkórè náà láti kọ́kọ́ ṣa àwọn èpò kúrò kí wọ́n sì dì wọ́n ní ìtí, kí a sì sun wọn, kí wọ́n sì kó àlìkámà sínú àká mi.’ ”

31. Jésù tún pa òwe mìíràn fún wọn: “Ìjọba ọ̀run dàbí èso hóró músítádì, èyí tí ọkùnrin kan mú tí ó gbìn sínú oko rẹ̀.

32. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ èso tí ó kéré púpọ̀ láàrin èṣo rẹ̀, ṣíbẹ̀ ó wá di ohun ọ̀gbìn tí ó tóbi jọjọ. Ó sì wá di igi tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì wá, wọ́n sì fi ẹ̀ka rẹ ṣe ìbùgbé.”

Ka pipe ipin Mátíù 13