26. Bí èṣù bá sì ń lé èṣù jáde, a jẹ́ wí pé, ó ń yapa sí ara rẹ̀. Ìjọba rẹ yóò ha ṣe le dúró?
27. Àti pé, bi èmi bá ń lé àwọn ẹ̀mí ẹ̀ṣù jáde nípa Béélísébúbù, nípa ta ni àwọn ènìyàn yín fi ń lé wọn jáde? Nítorí náà ni wọn yóò ṣe má ṣe ìdájọ́ yín.
28. Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé nípa ẹ̀mí Ọlọ́run ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí ẹ̀ṣù jáde, a jẹ́ pé ìjọba Ọlọ́run ti dé bá yín.
29. “Tàbí, báwo ni ẹnikẹ́ni ṣe lè wọ ilé alágbára lọ kí ó sì kó ẹrù rẹ̀, bí kò ṣe pé ó kọ́kọ́ de alágbára náà? Nígbà náà ni ó tó lè kó ẹrù rẹ̀ lọ.
30. “Ẹni tí kò bá wà pẹ̀lú mi, òun lòdì sí mi, ẹni tí kò bá mi kó pọ̀ ń fọ́nká.
31. Nítorí èyí, mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀rọ̀ òdì ni a yóò dárí rẹ̀ ji ènìyàn, ṣùgbọ́n ìsọ̀rọ̀-òdì-sí ẹ̀mí mímọ́ kò ní ìdáríjì.
32. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí Ọmọ ènìyàn, a ó dárí jì í, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́, a kì yóò dárí jì í, ìbá à ṣe ní ayé yìí tàbí ní ayé tí ń bọ̀.
33. “E ṣọ igi di rere, èso rẹ̀ a sì di rere tàbí kí ẹ sọ igi di búburú, èso rẹ a sì di búburú, nítorí nípa èso igi ni a ó fi mọ̀ ọ́n.
34. Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀, báwo ni ẹ̀yin tí ẹ jẹ búburú ṣe lè sọ̀rọ̀ rere? Ọkàn ènìyàn ni ó ń darí irú ọ̀rọ̀ tí ó lè jáde lẹ́nu rẹ̀.
35. Ẹni rere láti inú ìsúra rere ọkàn rẹ̀ ní i mú ohun rere jáde wá: àti ẹni búburu láti inú ìsúra búburú ni; mu ohun búburú jáde wá.
36. Ṣùgbọ́n, mo sọ èyí fún yín, ẹ̀yin yóò jíyìn gbogbo ìsọkúsọ yín ní ọjọ́ ìdájọ́.