Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 12:14-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Síbẹ̀ àwọn Farisí jáde lọ pe ìpàdé láti dìtẹ̀ mú un bí wọn yóò ṣe pa Jésù.

15. Ṣùgbọ́n Jésù mọ, ó yẹra kúrò níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì mú gbogbo àwọn aláìsàn láradá.

16. Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe sọ ẹni ti òun jẹ́.

17. Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àṣọtẹ́lẹ̀ èyí tí wòlíì Àìsáyà sọ nípa rẹ̀ pé:

18. “Ẹ wo ìránṣẹ mi ẹni tí mo yàn.Àyànfẹ́ mi ni ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi;èmi yóò fi ẹ̀mí mi fún un.Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ orílẹ̀-èdè gbogbo.

19. Òun kì yóò jà. bẹ́ẹ̀ ni kì yóò kígbe;ẹnikẹ́ni kì yóò gbọ́ ohùn rẹ ní ìgboro.

20. Ìyẹ́ tí ó fẹ́rẹ̀ fò ni kí yóò ṣẹ́,bẹ́ẹ̀ ni kì yóò pa iná fìtílà tí ó rú èéfín.Títí yóò fi mú ìdájọ́ dé ìsẹ́gun.

21. Ní orúkọ rẹ̀ ni gbogbo ayé yóò fi ìrètí wọn sí.”

22. Nígbà náà ni wọ́n mú ọkùnrin kan tó ni ẹmí-èṣù tọ̀ ọ́ wá, tí ó afọ́jú, tí ó tún ya odi. Jésù sì mú un lára dá kí ó le sọ̀rọ̀, ó sì ríran.

23. Ẹnu sì ya gbogbo àwọn ènìyàn. Wọ́n wí pé, “Èyí ha lè jẹ́ Ọmọ Dáfídì bí?”

24. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Farisí gbọ́ èyí, wọ́n wí pé, “Nípa Béélísébúbù nìkan, tí í ṣe ọba ẹ̀mí-èṣù ni ọkùnrin yìí fi lé àwọn ẹ̀mí-èṣù jáde”

25. Jésù tí ó mọ èrò wọn, ó wí fún wọn pé, “Ìjọba kíjọba tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ yóò parun, ìlú kílu tàbí ilé kílé tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ kì yóò dúró.

Ka pipe ipin Mátíù 12