Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 11:22-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Tírè àti Sídónì ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún yín.

23. Àti ìwọ Kápánámù, a ó ha gbé ọ ga sókè ọ̀run?, Rárá a ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ sí ipò òkú. Nítorí, ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú rẹ ní Sódómù, òun ìbá wà títí di òní.

24. Lóòótọ́ yóò sàn fún ilẹ̀ Sódómù ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún ìwọ lọ.”

25. Nígbà náà ni Jésù wí pé, “Mo yìn ọ Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, nítorí ìwọ ti fi òtítọ́ yìí pamọ́ fún àwọn tó jẹ́ ọlọgbọ́n àti amòyé, Ìwọ sì ti fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ wẹ́wẹ́.

26. Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, nítorí ó wù ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

27. “Ohun gbogbo ni Baba mi ti fi sí ìkáwọ́ mi. Kò sí ẹni tí ó mọ ọmọ bí kò se Baba, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnikẹ́ni tí ó mọ Baba, bí kò ṣe ọmọ, àti àwọn tí ọmọ yan láti fi ara hàn fún.

28. “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ tí a sì di ẹrù wí wúwo lé lórí, èmi yóò sì fún yín ní ìsinmi.

29. Ẹ gbé àjàgà mi wọ̀. Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi nítorí onínútútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmi, ẹ̀yin yóò sì fi ìsinmi fún ọkàn yín.

30. Nítorí àjàgà mi rọrùn ẹrù mi sì fúyẹ́.”

Ka pipe ipin Mátíù 11