Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 11:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn ìgbà tí Jésù sì ti parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá, ó ti ibẹ̀ rékọjá láti máa kọ́ni àti láti máa wàásù ní àwọn ìlú Gálílì gbogbo.

2. Nígbà tí Jòhánù gbọ́ ohun tí Kírísítì ṣe nínú ẹ̀wọ̀n, ó rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀

3. láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣe ìwọ ni ẹni tó ń bọ̀ wá tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?”

4. Jésù dáhùn ó wí pé, “Ẹ padà lọ, ẹ sì sọ fún Jòhánù ohun tí ẹ̀yin gbọ́, àti èyí tí ẹ̀yin rí.

Ka pipe ipin Mátíù 11