Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 1:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìran Jésù Kírísítì, ẹni tí í ṣe ọmọ Dáfídì, ọmọ Ábúráhámù:

2. Ábúráhámù ni baba Ísáákì;Ísáákì ni baba Jákọ́bù;Jákọ́bù ni baba Júdà àti àwọn arákùnrin rẹ̀,

3. Júdà ni baba Pérésì àti Ṣérà,Támárì sì ni ìyá rẹ̀,Pérésì ni baba Ésírónù:Ésírónù ni baba Rámù;

4. Rámù ni baba Ámínádábù;Ámínádábù ni baba Náhísónì;Náhísónì ni baba Sálímónì;

5. Sálímónì ni baba Bóásì, Ráhábù sí ni ìyá rẹ̀;Bóásì ni baba Óbédì, Rúùtù sí ni ìyá rẹ̀;Óbédì sì ni baba Jésè;

6. Jésè ni baba Dáfídì ọba.Dáfídì ni baba Sólómónì, ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ aya Húráyà tẹ́lẹ̀ rí.

7. Sólómónì ni baba Réhóbóámù,Réhóbóámù ni baba Ábíjà,Ábíjà ni baba Ásà,

8. Áṣà ni baba Jéhósáfátì;Jéhósafátì ni baba Jéhórámù;Jéhórámù ni baba Húsáyà;

9. Húsáyà ni baba Jótámù;Jótámù ni baba Áhásì;Áhásì ni baba Heṣekáyà;

10. Heṣekáyà ni baba Mánásè;Mánásè ni baba Ámónì;Ámónì ni baba Jósáyà;

11. Jósáyà sì ni baba Jékónáyà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ní àkókò ìkólọ sí Bábílónì.

12. Lẹ́yìn ìkólọ sí Bábílónì:Jékónáyà ni baba Selítílì;Selítílì ni baba Sérúbábélì;

13. Sèrérúbábélì ni baba Ábíúdì;Ábíúdì ni baba Élíákímù;Élíákímù ni baba Ásórì;

Ka pipe ipin Mátíù 1