Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 7:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ kan, àwọn Farisí olùkọ́ àti àwọn òfin tí ó wá láti Jerúsálémù péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀,

2. Wọ́n sì ṣe àkíyèsí wí pé díẹ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jésù ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun, èyí yìí ni wẹ ọwọ́.

3. (Àwọn Farisí, àti gbogbo àwọn Júù, bí wọ́n kò bá wẹ ọwọ́ wọn gidigidi, wọn kií jẹun nítorí wọ́n ti pa òfin àtọwọdọ́wọ́ àwọn àgbà mọ́.

4. Nígbà tí wọ́n bá sì ti ọjà dé sílé, wọn kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan oúnjẹ àfi tí wọ́n bá bomi wẹ ara wọn. Èyí sì jẹ́ ọ̀kan nínú ogunlọ́gọ̀ àpẹrẹ òfin àti ìlànà tí wọ́n ti dì mú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣẹ́yìn, bí i fífọ kọ́ọ̀bá, àwọn ìkòkò, àti kẹ́tù.)

5. Nítorí èyí àwọn Farisí àti àwọn olùkọ́ òfin béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èése tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò tẹ̀lé àwọn àṣà wa àtijọ́ nítorí wọ́n jẹun láì kọ́kọ́ wẹ ọwọ́ wọn.”

6. Jésù dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹyin àgàbàgebè yìí, òótọ́ ni wòlíì Àìṣáyà ń sọ nígbà tí ó ń ṣe àpèjúwe yín, tó wí pé:“ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi ẹnu wọn bu ọlá fún miṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnà sí mi.

7. Ìsìn wọn jẹ́ lásán,ìkọ́ni wọ́n jẹ́ kìkì dá òfin tí àwọn ènìyàn fi ń kọ́ni.’

8. Nítorí tí ẹ̀yin fi òfin Ọlọ́run sí apákan, ẹ̀yin ń tẹ̀lé àà àwọn ènìyàn.”

9. Ó si wí fún wọn: “Ẹyin sáà mọ̀ bí ẹ ti ń gbé òfin Ọlọ́run jù sẹ́yìn kí ẹ lè mú òfin tiyín ṣẹ.

10. Mósè fún un yín ní òfin yìí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ.’ Ó tún sọ pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ aburú sí baba tàbí ìyá rẹ̀ ní láti kú ni?’

11. Ṣùgbọ́n ẹyin wá yí i po pé ó dára bákan náà fún ọkùnrin kan bí kó bá tilẹ̀ pèsè fún àìní àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọ́n kí a sọ fún wọn pé, ‘Ẹ má ṣe bínú baba tàbí ìyá mi, n kò lè ràn yín lọ́wọ́ nísinsin yìí,’ nítorí tí mo ti fi èyí tí ǹ bá fi fún un yín fún Ọlọ́run.

12. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò si jẹ́ kí ó ṣe ohunkóhun fún baba tàbí iyá rẹ̀ mọ́.

13. Ẹ̀yin ń fi òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ti yín tí ẹ fi lélẹ̀, sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán àti ọ̀pọ̀ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń ṣe.”

14. Lẹ́yìn náà, Jésù pe ọ̀pọ̀ ènìyàn láti wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó sì wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí èyí ó yé e yín.

15. Kò sí ohunkóhun láti òde ènìyàn, tí ó wọ inú rẹ̀ lọ, tí ó lè sọ ọ́ di aláìmọ́, Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan tí ó ti inú rẹ jáde, àwọn wọ̀nyí ní ń sọ ènìyàn di aláìmọ́.

16. Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ kí ó gbọ́.”

Ka pipe ipin Máàkù 7