Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 6:6-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ẹnu si yà á nítorí àìgbàgbọ́ wọn. Lẹ́yìn náà, Jésù lọ sí àárin àwọn ìletò kéékèèkéé, ó sì ń kọ́ wọn.

7. Ó sì pe àwọn méjìlá náà sọ́dọ̀ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí rán wọn lọ ní méjì-méjì, Ó sì fi àṣẹ fún wọn lórí ẹ̀mí àìmọ́.

8. Òun sọ fún wọn pé, wọn kò gbọdọ̀ mú ohunkóhun lọ́wọ́, àfi ọ̀pá ìtilẹ̀ wọn. Wọn kò gbọdọ̀ mú oúnjẹ, àpò, tàbí owó lọ́wọ́.

9. Wọn kò tilẹ̀ gbodọ̀ mú ìpàrọ̀ bàtà tàbí aṣọ lọ́wọ́.

10. Jésù wí pé, “Ẹ dúró sí ilé kan ní ìletò kan. Ẹ má ṣe ṣípò padà láti ilé dé ilé, nígbà tí ẹ bá wà ní ìlú náà.

11. Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbà yín, tí kò sì gbọ́rọ̀ yín, nígbà tí ẹ̀yin bá jáde kúrò níbẹ̀, ẹ gbọn-eruku ẹṣẹ̀ yín síbẹ̀ fún ẹ̀rí fún wọn.”

12. Wọ́n jáde lọ láti wàásù ìrònúpìwàdà fún àwọn ènìyàn.

13. Wọ́n lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde. Wọ́n sì ń fi òróró kun orí àwọn tí ara wọn kò dá, wọ́n sì mú wọn láradá.

14. Láìpẹ́, ọba Hẹ́rọ́dù gbọ́ nípa Jésù, nítorí níbi gbogbo ni a ti ń sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀. Ọba náà rò pé, “Jòhánù Onítẹ́bọ́mì jínde kúrò nínú òkú, nítorí náà ni iṣẹ́ ìyanu ṣe ń ṣe láti ọwọ́ rẹ”

15. Àwọn mìíràn wí pé, “Èlíjà ní.”Àwọn mìíràn wí pé, “Wòlíì bí ọ̀kan lára àwọn àtijọ́ tó ti kú ló tún padà sáyé.”

16. Ṣùgbọ́n nígbà tí Hẹ́rọ́dù gbọ́ èyí, ó wí pé “Jòhánù tí mo tí bẹ́ lórí ni ó ti jíǹde kúrò nínú òkú.”

17. Hẹ́rọ́dù tikararẹ́ sá ti ránṣẹ mú Johanu, tìkaararẹ̀ sínu túbú nítorí Hẹrodíà aya Fílípì arákùnrin rẹ̀ nítorí tí ó fi ṣe aya.

18. Nítorí tí ó tẹnumọ́ ọn wí pé, “Kò tọ́ sí ọ láti fi ìyàwó arákùnrin rẹ ṣe aya.”

19. Nítorí náà ni Hẹ́rọ́díà ṣe ní ìn sínú, òun sì fẹ́ pa á, ṣùgbọ́n kò le se é.

20. Nítorí Hẹ́rọ́dù bẹ́rù Jòhánù, ó sì mọ̀ ọ́n ni olóòótọ́ ènìyàn àti ẹni mímọ́, ó sì ń tọ́jú rẹ̀. Nígbà tí Hẹ́rọ́dù gbọ́rọ̀ Jóhànù, ó ṣe ohun púpọ̀, ó sì fi olórí ní Gálílì.

21. Níkẹ̀yìn Hẹ́rọ́díà rí ààyè. Àkókò yìí ni ọjọ́ ìbí Hẹ́rọ́dù, òun sì pèṣè àsè ní ààfin ọba fún àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀: àwọn balógun àti àwọn jàǹkànjànkàn ní Gálílì.

Ka pipe ipin Máàkù 6