Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 6:26-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Inú ọba sì bàjẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n nítorí ìbúra rẹ, àti nítorí tí ó bá a jókòó pọ̀, kò sì fẹ́ kọ̀ fún un.

27. Nítorí èyí, ọba rán ẹ̀sọ ọ̀kan ó fi àṣẹ fún un pé, kí ó gbé orí Jòhánù wá. Ọkùnrin náà sì lọ, ó bẹ́ Jòhánù lórí nínú túbú.

28. Ó sì gbé orí Jòhánù sí wa nínú àwopọ̀kọ́. Ó sì gbé e fún ọmọbìnrin náà. Òun sì gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ.

29. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù gbọ́, wọ́n wá gbé òkú rẹ̀, wọ́n sì lọ tẹ́ ẹ sínú ibojì.

30. Àwọn àpósítélì ko ara wọn jọ sí ọ̀dọ̀ Jésù, wọ́n sí ròyìn ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe àti ohun gbogbo tí wọ́n ti kọ́ni.

31. Nígbà tí Jésù rí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ ti wọ́n sì ń bọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí kò sí ààyè fún wọn láti jẹun, ó si wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí a kúrò láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí fún ìgbà díẹ̀, kí a sì sinmi.”

32. Nítorí náà, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibi tí ó parọ́rọ́.

33. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ènìyàn ni o rí wọn nígbà tí wọ́n ń lọ. Àwọn wọ̀nyí sì tí ó wá láti ìlú ńlá gbogbo sáré gba etí òkun, wọ́n sì ṣe déédé wọ́n bí wọ́n ti gúnlẹ̀ ní èbúté.

34. Bí Jésù ti ń sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀ náà, ó bá ọ̀pọ̀ ènìyàn bí i tí àtẹ̀yìnwá, tí wọ́n ti ń dúró dè e. Ó káàánú fún wọn, nítorí wọ́n dàbí àgùntàn tí kò ní olùtọ́jú. Ó sì kọ́ wọn ni ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó yẹ kí wọ́n mọ̀.

35. Nígbà tí ọjọ́ sì ti bu lọ tán, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ ọ́ wa, wọ́n wí fún un pé, ibi aṣálẹ̀ ni ìbí yìí, ọjọ́ sì bù lọ tán.

36. “Rán àwọn ènìyàn wọ̀nyí láti lọ sí àwọn abúlé àti ìlú láti ra oúnjẹ fún ara wọn.”

37. Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ fún wọn ní oúnjẹ.”Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wí fún pé, “Eyí yóò ná wa tó owó iṣẹ́ lébìrà osù mẹ́jọ, Ṣe kí a lọ fi èyí ra búrẹ́dì fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn yìí láti jẹ.”

38. Jésù tún béèrè pé, “Ìṣù àkàrà mélòó ni ẹ̀yin ni lọ́wọ́? Ẹ lọ wò ó.”Wọ́n padà wá jíṣẹ́ pé, “Ìṣù àkàrà márùn ún àti ẹja méjì.”

39. Nígbà náà ni Jésù sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn náà kí a mú wọn jókòó lẹ́gbẹẹgbẹ́ lórí koríko.

Ka pipe ipin Máàkù 6