Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 6:12-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Wọ́n jáde lọ láti wàásù ìrònúpìwàdà fún àwọn ènìyàn.

13. Wọ́n lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde. Wọ́n sì ń fi òróró kun orí àwọn tí ara wọn kò dá, wọ́n sì mú wọn láradá.

14. Láìpẹ́, ọba Hẹ́rọ́dù gbọ́ nípa Jésù, nítorí níbi gbogbo ni a ti ń sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀. Ọba náà rò pé, “Jòhánù Onítẹ́bọ́mì jínde kúrò nínú òkú, nítorí náà ni iṣẹ́ ìyanu ṣe ń ṣe láti ọwọ́ rẹ”

15. Àwọn mìíràn wí pé, “Èlíjà ní.”Àwọn mìíràn wí pé, “Wòlíì bí ọ̀kan lára àwọn àtijọ́ tó ti kú ló tún padà sáyé.”

16. Ṣùgbọ́n nígbà tí Hẹ́rọ́dù gbọ́ èyí, ó wí pé “Jòhánù tí mo tí bẹ́ lórí ni ó ti jíǹde kúrò nínú òkú.”

17. Hẹ́rọ́dù tikararẹ́ sá ti ránṣẹ mú Johanu, tìkaararẹ̀ sínu túbú nítorí Hẹrodíà aya Fílípì arákùnrin rẹ̀ nítorí tí ó fi ṣe aya.

18. Nítorí tí ó tẹnumọ́ ọn wí pé, “Kò tọ́ sí ọ láti fi ìyàwó arákùnrin rẹ ṣe aya.”

19. Nítorí náà ni Hẹ́rọ́díà ṣe ní ìn sínú, òun sì fẹ́ pa á, ṣùgbọ́n kò le se é.

20. Nítorí Hẹ́rọ́dù bẹ́rù Jòhánù, ó sì mọ̀ ọ́n ni olóòótọ́ ènìyàn àti ẹni mímọ́, ó sì ń tọ́jú rẹ̀. Nígbà tí Hẹ́rọ́dù gbọ́rọ̀ Jóhànù, ó ṣe ohun púpọ̀, ó sì fi olórí ní Gálílì.

21. Níkẹ̀yìn Hẹ́rọ́díà rí ààyè. Àkókò yìí ni ọjọ́ ìbí Hẹ́rọ́dù, òun sì pèṣè àsè ní ààfin ọba fún àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀: àwọn balógun àti àwọn jàǹkànjànkàn ní Gálílì.

22. Nígbà náà, ni ọmọbìnrin Hẹ́rọ́díà wọlé tí ó jó. Inú Hẹ́rọ́dù àti àwọn àlèjò rẹ̀ dùn tóbẹ́ẹ̀ tí ọba sọ fún ọmọbìnrin náà pé,“Béèrè ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ lọ́wọ́ mi, èmi ó sì fi fún ọ.”

23. Ó sì búra fún un wí pé, “Ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́, ìbá à ṣe ìdajì ìjọba mi ni, èmi yóò fi fún ọ.”

24. Ó jáde lọ sọ fún ìyá rẹ̀ pé “Kí ní kí ń béèrè?”Ó dáhùn pé, “Orí Jòhánù Onítẹ̀bọmi.”

25. Ọmọbìnrin yìí sáré padà wá sọ́dọ̀ Hẹ̀rọ́dù ọba. Ó sì wí fún un pé, “Mo ń fẹ́ orí Jòhánù Onítẹ̀bọmi nísinsin-yìí nínú àwopọ̀kọ́.”

26. Inú ọba sì bàjẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n nítorí ìbúra rẹ, àti nítorí tí ó bá a jókòó pọ̀, kò sì fẹ́ kọ̀ fún un.

27. Nítorí èyí, ọba rán ẹ̀sọ ọ̀kan ó fi àṣẹ fún un pé, kí ó gbé orí Jòhánù wá. Ọkùnrin náà sì lọ, ó bẹ́ Jòhánù lórí nínú túbú.

28. Ó sì gbé orí Jòhánù sí wa nínú àwopọ̀kọ́. Ó sì gbé e fún ọmọbìnrin náà. Òun sì gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ.

Ka pipe ipin Máàkù 6