Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 6:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jésù fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí ìlú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀

2. Nígbà tí ó di ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sí sínágọ́gù láti kọ́ àwọn ènìyàn: ẹnu sì yà àwọn ènìyàn púpọ̀ tí ó gbọ́, wọ́n wí pé,“Níbo ni ọkùnrin yìí gbé ti rí nǹkan wọ̀nyí? Irú ọgbọ́n kí ni èyí tí a fi fún un, ti irú iṣẹ́ ìyanu báyìí ń ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe?

3. À bí kì í ṣe kápẹ́ríta ni? Àbí kì í ṣe ọmọ. Màríà àti arákùnrin Jákọ́bù àti Jósẹ́fù, Júdásì àti Símónì? Àbí kì í ṣe ẹni ti àwọn arábìnrin rẹ̀ ń gbé àárin wa níhìn ín?” Wọ́n sì kọsẹ̀ lára rẹ̀.

4. Nígbà náà, Jésù wí fún wọn pé, “A máa ń bu ọlá fún wòlíì níbi gbogbo àfi ní ìlú ara rẹ̀ àti láàrin àwọn ìdílé àti àwọn ẹbí òun pàápàá.”

5. Nítorí àìgbàgbọ́ wọn, òun kò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá láàrin wọn, àfi àwọn aláìsàn díẹ̀ tí ó gbé ọwọ́ lé lórí, tí wọ́n sì rí ìwòsàn.

6. Ẹnu si yà á nítorí àìgbàgbọ́ wọn. Lẹ́yìn náà, Jésù lọ sí àárin àwọn ìletò kéékèèkéé, ó sì ń kọ́ wọn.

7. Ó sì pe àwọn méjìlá náà sọ́dọ̀ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí rán wọn lọ ní méjì-méjì, Ó sì fi àṣẹ fún wọn lórí ẹ̀mí àìmọ́.

Ka pipe ipin Máàkù 6