Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 5:38-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

38. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, Jésù rí i pé gbogbo nǹkan ti dàrú. Ilé kún fún àwọn tí ń sọkún, àti àwọn tí ń pohùnréré ẹkún.

39. Ó wọ inú ilé lọ, Ó sì bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń sọkún tí ẹ sì ń pohunréré ẹkún? Ọmọbìnrin náà kò kú, ó sùn lásán ni.”

40. Wọ́n sì fi í rẹ́rín.Ṣùgbọ́n ó sọ fún gbogbo wọn láti bọ́ síta, ó mú baba àti ìyá ọmọ náà, àti àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ mẹ́ta. Ó sì wọ inú yàrá tí ọmọbìnrin náà gbé dùbúlẹ̀ sí.

41. Ó gba a ní ọwọ́ mú, ó sì wí pé, “Tàlítà kúùmì” (tí ó túmọ̀ sí, ọmọdébìnrin, díde dúró).

42. Lẹ́sẹ̀kan-náà, ọmọbìnrin náà sì dìde. Ó sì ń rìn, ẹ̀rù sì ba wọn, ẹnú sì ya àwọn òbí rẹ̀ gidigidi.

43. Jésù sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọn má ṣe sọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Ó sì wí fún wọn kí wọn fún ọmọbìnrin náà ní oúnjẹ.

Ka pipe ipin Máàkù 5