Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 5:31-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ rí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó rọ̀gbà yí ọ ká, ìwọ́ sì tún ń bèèrè ẹni tí ó fi ọwọ́ kàn ọ́?”

32. Ṣíbẹ̀, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí wò yíká láti rí ẹni náà, tí ó fi ọwọ́ kan òun.

33. Nígbà náà, obìnrin náà kún fún ìbẹ̀rù àti ìwárìrì nítorí ó ti mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lára òun. Ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ ohun tí òun ti ṣe.

34. Jésù sì wí fún un pé, “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ lára dá: Má a lọ ní àlàáfíà, ìwọ sì ti sàn nínú àrùn rẹ.”

35. Bí Jésù sì ti ń ba obìnrin náà sọ̀rọ̀, àwọn ìránṣẹ́ dé láti ilé Jáírù olorí sínágọ́gù wá, wọ́n wí fún un pé, ọmọbìnrin rẹ ti kú, àti pé kí wọn má ṣe yọ Jésù lẹ́nu láti wá, nítorí ó ti pẹ́ jù.

36. Ṣùgbọ́n bi Jésù ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún Jáírù pé, “Má bẹ̀rù, sá à gbà mí gbọ́ nìkan.”

37. Nígbà náà, Jésù dá ọ̀pọ̀ ènìyàn náà dúró. Kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀lé òun lẹ́yìn lọ ilé Jáírù, bí kò ṣe Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù.

38. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, Jésù rí i pé gbogbo nǹkan ti dàrú. Ilé kún fún àwọn tí ń sọkún, àti àwọn tí ń pohùnréré ẹkún.

39. Ó wọ inú ilé lọ, Ó sì bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń sọkún tí ẹ sì ń pohunréré ẹkún? Ọmọbìnrin náà kò kú, ó sùn lásán ni.”

40. Wọ́n sì fi í rẹ́rín.Ṣùgbọ́n ó sọ fún gbogbo wọn láti bọ́ síta, ó mú baba àti ìyá ọmọ náà, àti àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ mẹ́ta. Ó sì wọ inú yàrá tí ọmọbìnrin náà gbé dùbúlẹ̀ sí.

Ka pipe ipin Máàkù 5