Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 5:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Wọn lọ si apákejì adágún ní ẹba ilẹ̀ àwọn ará Gádárà.

2. Bí Jésù sì ti ń ti inú ọkọ̀ ojú omi jáde. Ọkùnrin kan tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́ jáde ti ibojì wá pàdé rẹ̀.

3. Ọkùnrin yìí ń gbé nínú ìbojì, kò sí ẹni tí ó lè dè é mọ́, kódà ẹ̀wọ̀n kò le dè é.

4. Nítorí pé nígbà púpọ̀ ni wọn ti ń fi ṣẹ́kẹ́sẹkẹ̀ dè é lọ́wọ́ àti ẹṣẹ̀, tí ó sì ń já a dànù kúrò ni ẹṣẹ rẹ. Kò sí ẹnìkan tí ó ní agbára láti káwọ́ rẹ̀.

5. Tọ̀sán-tòru láàrin àwọn ibojì àti ní àwọn òkè ni ó máa ń kígbe rara tí ó sì ń fi òkúta ya ara rẹ̀.

6. Nígbà tí ó sì rí Jésù látòkèrè, ó sí sáré lọ láti pàdé rẹ̀. Ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀.

7. Ó sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Kí ni ṣe tèmi tìrẹ, Jésù Ọmọ Ọlọ́run Ọ̀ga Ògo? Mo fi Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ má ṣe dá mi lóró.”

8. Nítorí tí Ó wí fún un pé, “Jáde kúrò lára ọkùnrin náà, ìwọ ẹ̀mí àìmọ́!”

9. Jésù sì bi í léèrè pé, “Kí ni orúkọ rẹ?”Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì dáhùn wí pé, “Líjíọ́nì, nítorí àwa pọ̀.”

Ka pipe ipin Máàkù 5