Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 4:20-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ṣùgbọ́n àwọn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, ní àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì gbà á lótìítọ́, wọ́n sì mú èso púpọ̀ jáde fún Ọlọ́run, ní ọgbọọgbọ̀n, ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùnún, gẹ́gẹ́ bí a ti gbìn ín sí ọkàn wọn.”

21. Ó si wí fún wọn pé, “A ha lè gbé fìtílà wá láti fí sábẹ́ òsùwọ̀n tàbí sábẹ́ àkéte? Rárá o, kí á máa sì se gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà?

22. Gbogbo ohun tí ó pamọ́ nísinsinyìí yóò hàn ní gbangba ní ọjọ́ kan, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí ó wà ní ìkòkọ̀, bí kò ṣe pé kí ó le yọ sí gbangba

23. Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.”

24. Ó sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ẹ maá kíyèsí ohun tí ẹ bà gbọ́ dáradára, nítorí òsùnwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ̀n náà ni a ó fi wọ̀n fún un yín àti jù bẹ́ẹ̀ lọ.

25. Nítorí ẹni tí ó bá ní, òun ni a ó tún fi fún síi àti lọ́wọ́ ẹni tí kò bá ń, ni a ó ti gba èyí náà tí ó ní.”

26. Ó sì tún ọ èyí pé, “Èyí ni a lè fí ìjọba Ọlọ́run wé. Ọkùnrin kan ń fúnrúgbìn sí ilẹ̀.

27. Lóru àti ní ọ̀sán, bóyá ó sùn tàbí ó dìdè, irúgbìn náà hù jáde, ó sì dàgbà, òun kò sì mọ̀ bí ó ti ṣẹlẹ̀.

Ka pipe ipin Máàkù 4