Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 4:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jésù sì tún bẹ̀rẹ̀ sí ń kọ́ní létí òkun Àwọn ijọ̀ ènìyàn tí ó yí i ká pọ̀ jọjọ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi bọ́ sínú ọkọ̀ ojú-omi, tí ó sì jókòó nínú rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun, nígbà tí àwọn ènìyàn sì wà ní ilẹ̀ létí òkun.

2. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé:

3. “Ẹ fi etí sílẹ̀! Ní ọjọ́ kan, afúnrúgbìn kan jáde lọ láti lọ fúnrúgbìn rẹ̀.

4. Bí ó ti ń fúnrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì ṣà á jẹ.

Ka pipe ipin Máàkù 4