Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 3:4-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Nígbà náà ni Jésù bèèrè lọ́wọ́ wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ó bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi bóyá láti ṣe rere, tàbí láti ṣe búburú! Láti gbà ẹ̀mí là, tàbí pa á run?” Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́ láìfèsì.

5. Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká pẹ̀lú ìbínú, ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí líle àyà wọn, ó sọ fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ jáde.” Ó nà án jáde, ọwọ́ náà sì bọ̀ sípò padà pátápátá.

6. Lójúkan-náà, àwọn Farisí jáde lọ, láti bá àwọn ọmọ ẹ̀yin Hẹ́rọ́dù gbìmọ̀ pọ̀, bí wọn yóò ṣe pa Jésù.

7. Jésù pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ yẹra kúrò níbẹ̀ lọ sí etí òkun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Gálílì àti Jùdíà sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

8. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìrpyìn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá láti Jùdíà, Jerúsálémù àti Ìdúmíà, àti láti apákejì odò Jọ́dání àti láti ihà Tírè àti Ṣídónì.

9. Nítorí ẹ̀rọ̀, Jésù sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ lati sètò ọkọ̀ ojú omi kekere kan sílẹ̀ fún un láti lọ, láti lé àwọn ẹ̀rọ̀ sẹ́yìn.

10. Nítorí tí ó mú ọ̀pọ̀ ènìyàn láradá lọ́jọ́ náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aláìsàn ló yí i ká, tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti fi ọwọ́ kàn án.

11. Ìgbàkúùgbà tí àwọn tí ó kún fún ẹ̀mí àìmọ́ bá ti fojú gán-án ní rẹ̀, wọ́n á wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Wọn a sì kígbe lóhùn-rara wí pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run.”

12. Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn gidigidi, kí wọn má ṣe fi òun hàn.

13. Jésù gun orí òkè lọ ó gun orí òkè lọ, ó sì pe àwọn kan tí ó yàn láti wà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá.

14. Ó yan àwọn méjìlá-ó pè wọ́n ní apostẹli-kí wọ́n kí ó lè wà pẹ̀lú rẹ̀, àti kí wọn kí ó lè lọ láti wàásù

15. àti láti lágbára láti lé àwọn ẹ̀mí Èsù jáde.

16. Wọ̀nyí ni àwọn méjìlá náà tí ó yàn, Ṣímóní (ẹni ti ó sọ àpèlé rẹ̀ ní Pétérù)

17. Jákọ́bù ọmọ Sébédè àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀ (àwọn ẹni tí Jésù sọ àpèlé wọ́n ní Bóánájì, èyí tí ó túmọ̀ sí àwọn ọmọ àrá).

18. Àti Ańdérù, Fílípì, Bátólómíù, Mátíù, Tómásì, Jákọ́bù (ọmọ Álíféù), Tádéù, Símónì (ọ̀kan nínú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó fẹ́ ará Kénánì tí ó fi ìjàngbọ̀n dojú ìjọba Rómù bolẹ̀)

Ka pipe ipin Máàkù 3