Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 3:28-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Lóòótọ́ ní mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni a ó dárí jin àwọn ọmọ ènìyàn, àti gbogbo ọ̀rọ̀ òdì.

29. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́, kì yóò rí ìdáríjì títí ayé, ṣùgbọ́n ó wà nínú èwù ẹ̀bi àìnípẹ̀kun.”

30. Òun sọ eléyìí fún wọn, nítorí tí wọ́n sọ pé, “Nípa agbára ẹ̀mí Èṣù ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.”

31. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ìyá àti àwọn arákùnrin rẹ̀ dé. Wọ́n dúró lóde, wọ́n sì rán ẹnìkan sí i pé kí ó pè é wá.

32. Àwọn ènìyàn tí wọ́n jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Ìyá àti àwọn arákùnrin rẹ wà lóde.”

33. Ṣùgbọ́n ó dá wọn lóhùn wí pé, “Ta ni í ṣe ìyá mi tàbí àwọn arákùnrin mi?”

Ka pipe ipin Máàkù 3