Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 3:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Jésù wá sí sínágọ́gù. Sì kíyèsí i ọkùnrin kan wà níbẹ̀, tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ.

2. Àwọ́n kan nínú wọn sì ń wa ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kan Jésù, ítorí náà, wọn ń sọ Ọ́ bí yóò u un láradá ní ọjọ́ ìsinmi.

3. Jésù wí fún ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ náà pé, “Dìde dúró ní iwájú ìjọ ènìyàn.”

4. Nígbà náà ni Jésù bèèrè lọ́wọ́ wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ó bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi bóyá láti ṣe rere, tàbí láti ṣe búburú! Láti gbà ẹ̀mí là, tàbí pa á run?” Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́ láìfèsì.

5. Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká pẹ̀lú ìbínú, ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí líle àyà wọn, ó sọ fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ jáde.” Ó nà án jáde, ọwọ́ náà sì bọ̀ sípò padà pátápátá.

6. Lójúkan-náà, àwọn Farisí jáde lọ, láti bá àwọn ọmọ ẹ̀yin Hẹ́rọ́dù gbìmọ̀ pọ̀, bí wọn yóò ṣe pa Jésù.

7. Jésù pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ yẹra kúrò níbẹ̀ lọ sí etí òkun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Gálílì àti Jùdíà sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

8. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìrpyìn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá láti Jùdíà, Jerúsálémù àti Ìdúmíà, àti láti apákejì odò Jọ́dání àti láti ihà Tírè àti Ṣídónì.

9. Nítorí ẹ̀rọ̀, Jésù sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ lati sètò ọkọ̀ ojú omi kekere kan sílẹ̀ fún un láti lọ, láti lé àwọn ẹ̀rọ̀ sẹ́yìn.

10. Nítorí tí ó mú ọ̀pọ̀ ènìyàn láradá lọ́jọ́ náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aláìsàn ló yí i ká, tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti fi ọwọ́ kàn án.

Ka pipe ipin Máàkù 3