Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 16:6-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù: Ẹ̀yin ń wá Jésì tí Násárẹ́tì, tí a kàn mọ́ àgbélébùú. Ó jíǹde! Kò sí níhìnín yìí mọ́, Ẹ wo ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.

7. Ṣùgbọ́n ẹ lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ títí kan Pétérù wí pé, ‘Òun ti ń lọ ṣíwájú yín sí Gálílì. Ibẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti rí i, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún yín.’ ”

8. Wọ́n sá jáde lọ kánkán, wọn sì sáré kúrò ní ibi ibojì náà, nítorí tí wọ́n wárìrì; ẹ̀rù sì bà wọn gidigidi; wọn kò wí ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni, nítorí ẹ̀rù bá wọ́n.

9. Nìgbà tí Jésù jíǹde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ní ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sè, ó kọ́ fi ara hàn fun Màríà Magidalénì, ni ara ẹni tí ó ti lé ẹ̀mi Èsù méje jáde.

10. Òun sì lọ sọ fún àwọn tí ó ti ń bá a gbé, bí wọn ti ń gbààwẹ̀, tí wọ́n sì ń sọkún.

11. Àti àwọn, nígbà tí wọ́n sì gbọ́ pé ó ti di alààyè, àti pé, òun ti rí i, wọn kò gbàgbọ́.

12. Lẹ́yìn èyí, ó sì fi ara hàn fún àwọn méjì ní ọ̀nà mìíràn, bí wọ́n ti ń rìn ní ọ̀nà, tí wọ́n sì ń lọ sí ìgbéríko.

13. Nígbà tí wọ́n sì mọ ẹni tí i ṣe, wọ́n sì lọ ròyìn fún àwọn ìyókù, ṣíbẹ̀, àwọn ìyókù kò gbà wọ́n gbọ́.

14. Lẹ́yìn náà, Jésù fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn mọ́kànlá níbi tí wọ́n ti jìjọ ń jẹun; Ó sì bá wọn wí fún àìgbàgbọ́ àti ọkàn líle wọn, nítorí wọn kò gba ẹ̀rí àwọn tí ó ti rí i lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀ gbọ́.

Ka pipe ipin Máàkù 16