Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 16:2-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ní kùtùkùtù ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sè, wọ́n wá sí ibi ibojì nigbà tí òòrùn bẹ̀rẹ̀ sí yọ,

3. wọn sì ń bi ara wọn léèrè pé, “Ta ni yóò yí òkúta náà kúrò lẹ́nu ibojì fún wa?”

4. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn sì wò ó, wọ́n rí i pé a ti yí òkúta tí ó tóbi gidigidi náà kúrò.

5. Nígbà tí wọ́n sì wọ inú ibojì náà, wọ́n rí ọ̀dọ́mọkùnrin kàn tí ó wọ aṣọ funfun, ó jókòó ní apá ọ̀tún, ẹnú sì yà wọn.

6. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù: Ẹ̀yin ń wá Jésì tí Násárẹ́tì, tí a kàn mọ́ àgbélébùú. Ó jíǹde! Kò sí níhìnín yìí mọ́, Ẹ wo ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.

7. Ṣùgbọ́n ẹ lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ títí kan Pétérù wí pé, ‘Òun ti ń lọ ṣíwájú yín sí Gálílì. Ibẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti rí i, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún yín.’ ”

8. Wọ́n sá jáde lọ kánkán, wọn sì sáré kúrò ní ibi ibojì náà, nítorí tí wọ́n wárìrì; ẹ̀rù sì bà wọn gidigidi; wọn kò wí ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni, nítorí ẹ̀rù bá wọ́n.

9. Nìgbà tí Jésù jíǹde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ní ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sè, ó kọ́ fi ara hàn fun Màríà Magidalénì, ni ara ẹni tí ó ti lé ẹ̀mi Èsù méje jáde.

10. Òun sì lọ sọ fún àwọn tí ó ti ń bá a gbé, bí wọn ti ń gbààwẹ̀, tí wọ́n sì ń sọkún.

Ka pipe ipin Máàkù 16