Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 14:7-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Nígbà gbogbo ni àwọn talákà wà ní àárin yín, wọ́n sì ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ yín. Ẹ sì lè ṣe oore fún wọn nígbàkugbà tí ẹ bá fẹ́.

8. Ó ti ṣe èyí tí ó lè ṣe, Ó ti fi òróró kùn mí ni ara ní ìmúra sílẹ̀ de ìgbà tí wọn yóò sin òkú mi.

9. Lóótọ́ ni mo wí fún un yín, níbikíbi tí wọ́n bá ti wàásù mi, ní gbogbo ayé, wọn kò ní ṣe aláìsọ ohun tí obìnrin yìí ṣe pẹ̀lú ní ìrántí rẹ̀.”

10. Nígbà náà ni Júdásì Ìsíkáríọtù, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfàá, láti ṣètò bí yóò ti fi Jésù lé wọn lọ́wọ́.

11. Inú wọn dùn láti gbọ́ èyí, wọ́n sì pinnu láti fún un ní owó. Nítorí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àkókò tí ó rọrùn tí òun yóò fi Jésù lé wọn lọ́wọ́.

12. Ní ọjọ́ kìnínní àjọ̀dún ìrékọjá tí í ṣe ọjọ́ tí wọ́n máa ń pa ẹran àgùntàn fún ìrúbọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jésù bi í léèrè pé, “Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a lọ pèṣè sílẹ̀ tí ìwọ yóò ti jẹ àṣè ìrékọjá?”

13. Ó rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sínú ìlú, ọkùnrin kan tó ru iṣà omi yóò pàdé yín, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

14. Ilé tí ọkùnrin náà bá wọ̀, kí ẹ wí fún baale náà pé, ‘Olùkọ́ rán wa pé: Ní bo ni gbàngàn àpèjẹ náà gbé wa, níbi tí èmi yóò gbé jẹ àṣè ìrékọja pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi?’

15. Òun yóò sì mú un yín lọ sí gbàngàn ńlá kan lókè ilé náà, tí a ti ṣe lọ́sọ́. Níbẹ̀ ni kí ẹ pèṣè sílẹ̀ dè wá.”

16. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì jáde lọ àárin ìlú. Wọ́n bá gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí Jésù tí sọ fún wọn. Wọ́n sì pèsè àṣè ìrékọjá.

17. Nígbà tí ó di alẹ́, Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé ṣíbẹ̀.

18. Bí wọ́n sì ti jókòó yí tábìlì ká, tí wọ́n ń jẹun, Jésù wí pé, “Lóòtọ́ ni mo wí fún un yín, ọ̀kan nínú ẹ̀yin tí ẹ ń bá mi jẹun yìí ni yóò fí mí hàn.”

19. Ọkàn wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í dàrú. Olúkúlùkù sì ń bi í ní ọkọ̀ọ̀kan wí pé, “Dájúdájú, kì í ṣe èmi?”

20. Ó sì dáhùn wí pé, “Ọ̀kan nínú ẹ̀yin méjìlá tí ó ń bá mi jẹun nísinsin yìí ni.

21. Ní tòótọ́ Ọmọ-Ènìyàn ń lọ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀: Ṣùgbọ́n ègbé ní fún ọkùnrin náà, láti ọwọ́ ẹni tí a ti fi Ọmọ-Ènìyàn hàn. Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i rárá.”

Ka pipe ipin Máàkù 14