Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 14:23-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ó sì tún gbé ago wáìnì, ó gbàdúrà ọpẹ́ sí Ọlọ́run. Ó sì gbé e fún wọn. Gbogbo wọn sì mu nínú rẹ̀.

24. Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi ti májẹ̀mú túntún, tí a ta sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.

25. Lóótọ̀ ni mo wí fún un yín, èmi kò tún ní mu wáìnì mọ́ títí yóò fi di ọjọ́ náà tí Èmi yóò mu ún ní titun nínú ìjọba Ọlọ́run.”

26. Lẹ́yìn náà wọ́n kọ orin, wọ́n sì gun orí òkè ólífì lọ.

Ka pipe ipin Máàkù 14