Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 14:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn ọjọ́ méjì ni Àjọ ìrékọjá àti àjọ tí wọ́n ń fi àkàrà àìwú se ku ọ̀túnla. Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́-òfin sì ń wá ọ̀nà láti mú Jésù ní ìkọ̀kọ̀, kí wọn sì pa á.

2. Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé, “A kò ní mú un ní ọjọ́ Àjọ, kí àwọn ènìyàn má bá á fa ìjàngbọ̀n.”

3. Nígbà tí ó sì wà ní Bẹ́tanì ni ilé Símónì adẹ́tẹ̀ bí ó ti jókòó ti oúnjẹ, obìnrin kan wọlé, ti òun ti ìgò òróró ìpara olówó iyebíye, ó sí ìgò náà, ó sì da òróró náà lé Jésù lórí.

4. Àwọn kan nínú àwọn tí ó jókòó ti tábìlì kún fún ìbànújẹ́. Wọ́n sì ń bi ara wọn pé, “Nítorí kí ni a ṣe fi òróró yìí ṣòfò?

5. Òun ìbá tà á ju owó iṣẹ́ ọdún kan lọ, kí ó sì fi owó rẹ̀ ta àwọn talákà lọ́rẹ.” Báyìí ni wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ gún obìnrin náà lára.

6. Ṣùgbọ́n Jésù wí fún pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, kí ni ẹ ń yọ ọ́ lẹ́nu fún ṣé? Nítorí tí ó ṣe ohun rere sí mi?

7. Nígbà gbogbo ni àwọn talákà wà ní àárin yín, wọ́n sì ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ yín. Ẹ sì lè ṣe oore fún wọn nígbàkugbà tí ẹ bá fẹ́.

8. Ó ti ṣe èyí tí ó lè ṣe, Ó ti fi òróró kùn mí ni ara ní ìmúra sílẹ̀ de ìgbà tí wọn yóò sin òkú mi.

9. Lóótọ́ ni mo wí fún un yín, níbikíbi tí wọ́n bá ti wàásù mi, ní gbogbo ayé, wọn kò ní ṣe aláìsọ ohun tí obìnrin yìí ṣe pẹ̀lú ní ìrántí rẹ̀.”

10. Nígbà náà ni Júdásì Ìsíkáríọtù, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfàá, láti ṣètò bí yóò ti fi Jésù lé wọn lọ́wọ́.

11. Inú wọn dùn láti gbọ́ èyí, wọ́n sì pinnu láti fún un ní owó. Nítorí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àkókò tí ó rọrùn tí òun yóò fi Jésù lé wọn lọ́wọ́.

12. Ní ọjọ́ kìnínní àjọ̀dún ìrékọjá tí í ṣe ọjọ́ tí wọ́n máa ń pa ẹran àgùntàn fún ìrúbọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jésù bi í léèrè pé, “Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a lọ pèṣè sílẹ̀ tí ìwọ yóò ti jẹ àṣè ìrékọjá?”

Ka pipe ipin Máàkù 14