Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 11:22-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Jésù sì dáhùn pé, “Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run,

23. Lóòótọ́ ni mò wí fún un yín, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè ‘ṣí ìdí, gbé ara rẹ sọ sínú òkun’ ti kò sí ṣe iyèméjì nínú ọkàn rẹ̀ ṣùgbọ́n ti ó gbàgbọ́ pé ohun tí òun wí yóò ṣẹ, yóò rí bẹ́ẹ̀ fún un.

24. Torí náà, mo wí fún yín ohunkóhun tí ẹ bá béèrè fún nínú àdúrà, ẹ ní ìgbàgbọ́ pé, ó tí tẹ̀ yín lọ́wọ́, yóò sì jẹ́ ti yín.

25. nígbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ kọ́kọ́ dáríjì ẹni tí ó ṣẹ̀ yín. Baba yín lọ́run yóò dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiyín náà jì yín.”

26. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá dáríjì, Baba yín ti ń bẹ ni ọ̀run kí yóò dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín

27. Lẹ́yìn èyí, wọ́n tún padà sí Jerúsálémù.Bí Jésù ti ń rìn kíri ni tẹ́ḿpílì, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn tí ń kọ́ni ni òfin pẹ̀lú àwọn àgbààgbà Júù wá sọ́dọ̀ rẹ̀.

28. Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Àṣẹ wo ni ó fi ń se nǹkan yìí? Ta ni ó sì fún ọ ni àṣẹ yìí láti máa ṣe nǹkan wọ̀nyìí?”

29. Jésù dá wọn lóhùn pé, “Èmi yóò sọ fún un yín bí ẹ bá lè dáhùn ìbéèrè mi yìí.”

30. Ìtẹ̀bọmi Jòhánù láti ọ̀run wa ni, tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn? “Ẹ dá mi lóhùn!”

31. Wọ́n bá ara wọn jíjòrò pé: “Bí a bá wí pé Ọlọ́run ni ó rán an wá nígbà náà yóò wí pé, ‘nígbà tí ẹ mọ̀ bẹ́ẹ̀, èéṣe tí ẹ kò fi gbà à gbọ?’

32. Ṣùgbọ́n bí a bá sọ wí pé Ọlọ́run kọ́ ló rán an, nígbà náà àwọn ènìyàn yóò bẹ̀rẹ̀ rògbòdìyàn. Nítorí pé gbogbo ènìyàn ló gbàgbọ́ pé wòlíì gidi ni Jòhánù.”

33. Nítorí náà, Wọ́n kọjú sí Jésù wọn sì dáhùn pé, “Àwa kò mọ̀.”Nígbà náà ni Jésù wí pé, “Níwọ̀n ìgbà tí ẹ kò lè dáhùn ìbéèrè mi, Èmi náà kì yóò sọ fún yín àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.”

Ka pipe ipin Máàkù 11