Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 11:15-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Nígbà ti wọ́n padà sí Jerúsálémù, ó wọ inú tẹ́ḿpílì. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní lé àwọn oníṣòwò àti àwọn oníbárà wọn síta. Ó ti tábìlì àwọn tí ń pààrọ̀ owó nínú tẹ́ḿpílì ṣubú. Bákan náà ni ó ti ìjókòó àwọn tí ń ta ẹyẹlé lulẹ̀.

16. Kò sì gba ẹnikẹ́ni láàyè láti gbé ẹrù ọjà títa wọlé.

17. Gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ wọn, ó wí pé, “Ṣe a kò ti kọ ọ́ pé:“ ‘Ilé àdúrà ni a o máa pe ilé mi,ní gbogbo òrilẹ̀ èdè’?Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ọlọ́ṣà.”

18. Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́-òfin gbọ́ ohun tí ó ti ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ń gbà èrò bí wọn yóò ti ṣe pa á. Wọ́n bẹ̀rù rògbòdìyàn tí yóò bẹ́ sílẹ̀, nítorí tí àwọn ènìyàn ní ìgbóná-ọkàn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀.

19. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, bí ìṣe wọn, Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde kúrò ní ìlú Jerúsálémù.

20. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti ń kọjá lọ, wọ́n rí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí Jésù fi bú. Wọ́n rí i pé ó ti gbẹ tigbòǹgbò-tigbòǹgbò.

21. Pétérù rántí pé Jésù ti bá igi náà wí. Nígbà náà ni ó sọ fún Jésù pé, “Rábì, Wò ó! Igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ìwọ fi bú ti gbẹ!”

22. Jésù sì dáhùn pé, “Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run,

23. Lóòótọ́ ni mò wí fún un yín, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè ‘ṣí ìdí, gbé ara rẹ sọ sínú òkun’ ti kò sí ṣe iyèméjì nínú ọkàn rẹ̀ ṣùgbọ́n ti ó gbàgbọ́ pé ohun tí òun wí yóò ṣẹ, yóò rí bẹ́ẹ̀ fún un.

Ka pipe ipin Máàkù 11