Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 10:41-52 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

41. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá ìyókù gbọ́ ohun tí Jákọ́bù àti Jòhánù béèrè, wọ́n bínú.

42. Nítorí ìdí èyí, Jésù pè wọ́n sọ́dọ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé, àwọn ọba àti àwọn kèfèrí ń lo agbára lórí àwọn ènìyàn.

43. Ṣùgbọ́n láàrin yín ó yàtọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ di olórí nínú yín gbọdọ̀ ṣe ìránṣẹ́.

44. Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ di aṣáájú nínú yín gbọdọ̀ ṣe ìránṣẹ́ gbogbo yín

45. Nítorí, Èmi, Ọmọ ènìyàn kò wá sí ayé kí ẹ lè ṣe ìránṣẹ́ fún mi, ṣùgbọ́n láti lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, àti láti kú fún ìràpadà ọ̀pọ̀ ènìyàn.”

46. Wọ́n dé Jẹ́ríkò, bí Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn ti fẹ́ kúrò ní ìlú Jẹ́ríkò, ọkùnrin afọ́jú kan, Bátíméù, ọmọ Tíméù jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà ó ń sagbe.

47. Nígbà tí Bátiméù gbọ́ pé Jésù ti Násárẹ́tì wà nítòsí, o bẹ̀rẹ̀ sí kígbe lóhùn rara pé, “Jésù ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún mi.”

48. Àwọn tó wà níbẹ̀ kígbe mọ́ ọn pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́.” Ṣùgbọ́n dípò kí ó pa ẹnu mọ́, ṣe ló ń kígbe lóhùn rara pé, “Jésù ọmọ Dáfídì ṣàánú fún mi.”

49. Nígbà tí Jésù gbọ́ igbe rẹ̀, ó dẹṣẹ̀ dúró lójú-ọ̀nà, ó sì wí pé, “Ẹ pè é kí ó wá sọ́dọ̀ mi.” Nítorí náà wọ́n pe ọkùnrin afọ́jú náà, wọ́n wí pé, “Tújúká!, dìde lórí ẹsẹ̀ rẹ! Ó ń pè ọ́.”

50. Lẹ́sẹ̀kan-náà, Bátíméù bọ́ aṣọ rẹ̀ sọnù, ó fò sókè, ó sì wá sọ́dọ̀ Jésù.

51. Jésù béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ìwọ fẹ́ kí èmi kí ó ṣe fún ọ?”Afọ́jú náà dáhùn pé, “Rábì, jẹ́ kí èmi ki o ríran.”

52. Jésù wí fún un pé, “Má a lọ, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ láradá.” Lẹ́ṣẹ̀kẹṣẹ̀, ọkùnrin afọ́jú náà ríran ó sì ń tẹ̀lé Jésù lọ ní ọ̀nà.

Ka pipe ipin Máàkù 10