Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 10:38-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

38. Ṣùgbọ́n Jésù dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò mọ ohun tí ẹ̀ ń béèrè! Ṣe ẹ lè mu nínú ago kíkorò tí èmi ó mú tàbí a lè bamitíìsì yín pẹ̀lú irú ìbamitíìsì ìjiyà tí a ó fi bamitíìsì mi?”

39. Àwọn méjèèjì dáhùn pé, “Àwa pẹ̀lú lè ṣe bẹ́ẹ̀.” Jésù wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó mu ago ti èmi yóò mu, àti bamitíìsímù tí a sí bamitíìsì mi ni a ó fi bamitíìsì yín,

40. ṣùgbọ́n láti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi àti ní ọwọ́ ọ̀sì mi kì ì ṣe ti èmi láti fi fún ni: bí kò ṣe fún àwọn ẹni tí a ti pèṣè rẹ̀ sílẹ̀ fún.”

41. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá ìyókù gbọ́ ohun tí Jákọ́bù àti Jòhánù béèrè, wọ́n bínú.

42. Nítorí ìdí èyí, Jésù pè wọ́n sọ́dọ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé, àwọn ọba àti àwọn kèfèrí ń lo agbára lórí àwọn ènìyàn.

43. Ṣùgbọ́n láàrin yín ó yàtọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ di olórí nínú yín gbọdọ̀ ṣe ìránṣẹ́.

44. Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ di aṣáájú nínú yín gbọdọ̀ ṣe ìránṣẹ́ gbogbo yín

45. Nítorí, Èmi, Ọmọ ènìyàn kò wá sí ayé kí ẹ lè ṣe ìránṣẹ́ fún mi, ṣùgbọ́n láti lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, àti láti kú fún ìràpadà ọ̀pọ̀ ènìyàn.”

46. Wọ́n dé Jẹ́ríkò, bí Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn ti fẹ́ kúrò ní ìlú Jẹ́ríkò, ọkùnrin afọ́jú kan, Bátíméù, ọmọ Tíméù jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà ó ń sagbe.

47. Nígbà tí Bátiméù gbọ́ pé Jésù ti Násárẹ́tì wà nítòsí, o bẹ̀rẹ̀ sí kígbe lóhùn rara pé, “Jésù ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún mi.”

48. Àwọn tó wà níbẹ̀ kígbe mọ́ ọn pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́.” Ṣùgbọ́n dípò kí ó pa ẹnu mọ́, ṣe ló ń kígbe lóhùn rara pé, “Jésù ọmọ Dáfídì ṣàánú fún mi.”

Ka pipe ipin Máàkù 10