Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 10:10-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jésù nìkan wà nínú ilé pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n tún béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa ohun kan náà.

11. Jésù túbọ̀ ṣe àlàyé fún wọn pé, “Nígbà tí ọkùnrin kan bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ tí ó bá sì fẹ ẹlòmíràn, irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ ṣe panṣágà sí obìnrin tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé níyàwó.

12. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí obìnrin kan bá kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì fẹ́ ọkùnrin mìíràn, irú obìnrin bẹ́ẹ̀ ṣe panṣágà.”

13. Lẹ́yìn èyí, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ tọ Jésù wá kí ó lè súre fún wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kígbe mọ́ àwọn tí ń gbé àwọn ọmọdé wọ̀nyí bọ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ yọ Jésù lẹ́nu rárá.

14. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù rí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, inú rẹ̀ kò dùn sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Nítorí náà, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé kékeré wá sọ́dọ̀ mi. Ẹ má ṣe dá wọn lẹ́kun nítorí pé irú wọ́n ni ìjọba Ọlọ́run.

15. Mo ń sọ òótọ́ fún un yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti mọ̀, pé, ẹni tí kò bá wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bi ọmọ kékeré, a kì yóò fún un láàyè láti wọ ìjọba rẹ̀.”

16. Nígbà náà, Jésù gbé àwọn ọmọ náà lé ọwọ́ rẹ̀, ó gbé ọwọ́ lé orí wọn. Ó sì súre fún wọn.

17. Bí Jésù ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò kan, ọkùnrin kan sáré wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sì kúnlẹ̀, ó béèrè pé, “Olùkọ́ rere, kí ni èmi yóò ṣe láti jogún ìyè àìnipẹ̀kun?”

18. Jésù béèrè pé, Arákùnrin, “Èéṣe tí o fi ń pè mí ní ẹni rere? Ẹni rere kan kò sí Ọlọ́run nìkan ni ẹni rere.

19. Ìwọ mọ àwọn òfin bí i: Má ṣe pànìyàn, má ṣe panṣágà, má ṣe jalè, má ṣe purọ́, má ṣe rẹ́ ọmọnìkejì jẹ, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ.”

Ka pipe ipin Máàkù 10