Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 1:2-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé wòlíì Àìṣáyà pé:“Èmi yóò ran oníṣẹ́ mí ṣíwájú rẹ,Ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe.”

3. “Ohùn ẹnìkan tí ń kígbe ní ihà,‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,ẹ se ojú-ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ”

4. Jòhánù dé, ẹni tí ó ń tẹnibọmi ní ihà, tí ó sì ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.

5. Gbogbo àwọn tí ń gbé ní agbègbè Jùdíà, àti gbogbo ènìyàn Jerúsálémù jáde tọ̀ ọ́ lọ, a sì ti ọwọ́ rẹ̀ tẹ gbogbo wọn bọmi ni odò Jọ́dánì, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

6. Jòhánù sì wọ ẹ̀wù tí a fi irun ràkúnmí hun. Ó sì lo ìgbànú awọ. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀.

7. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù wí pé, “Ẹnìkan tí ó tóbi jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹṣẹ̀ ẹni tí èmi kò tó ẹni tí ń tú.

8. Èmi ń fi omi se ìtẹ̀bọmi yín, ṣùgbọ́n Òun yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ se ìtẹ̀bọmi yín.”

9. Ó sì ṣe ní ọjọ́ kan Jésù ti Násárẹ́tì ti Gálílì jáde wá, a sì ti ọwọ́ Jòhánù tẹ̀ Ẹ bọmi ní odò Jọ́dánì.

10. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí Jésù ń ti inú omi jáde wá, ó rí ọ̀run tí ó sí sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ bí àdàbà sọkalẹ̀ lé E lórí.

11. Ohùn kan sì ti ọ̀run wá wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi, ìwọ ni ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”

12. Lẹ́sẹ̀kan-náà, Ẹ̀mí Mímọ́ sì darí Jésù sí ihà,

13. Ó sì wà níbẹ̀ fún ogójì ọjọ́. A sì fi Í lé Èṣù lọ́wọ́ láti dán an wò. Àwọn ańgẹ́lì sì wá ṣe ìtọ́jú Rẹ̀.

14. Lẹ́yìn ìgbà tí ọba Hẹ́rọ́dù ti fi Jòhánù sínú ẹ̀wọ̀n tan, Jésù lọ sí Gálílì, ó ń wàásù ìyìn rere ti ìjọba Ọlọ́run.

15. Ó sì kéde wí pé, “Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dèdè. Ẹ yípadà kúró nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì gba ìyìnrere yìí gbọ́.”

16. Ní ọjọ́ kan, bí Jésù ti ń rìn létí òkun Gálílì, Ó rí Ṣímónì àti Ańdérù arákùnrin rẹ̀, wọ́n ń fi àwọ̀n wọn pẹja torí pé Apẹja ni wọ́n.

Ka pipe ipin Máàkù 1