Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 9:45-62 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

45. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà kò yé wọn, ó sì ṣú wọn lójú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì mọ̀ ọ́n: ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti bèèrè ìdí ọ̀rọ̀ náà.

46. Iyàn kan sì dìde láàrin wọn, ní ti ẹni tí yóò ṣe olórí nínú wọn.

47. Nígbà tí Jésù sì mọ ìrò ọkàn wọn, ó mú ọmọdé kan, ó gbé e jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀.

48. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọdé yìí nítorí orúkọ mi, ó gbà mí: àti ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi: nítorí ẹni tí ó bá kéré jù nínú gbogbo yín, òun náà ni yóò pọ̀.”

49. Jòhánù sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́, àwá rí ẹnìkan ó ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èsù jáde; àwa sì dá a lẹ́kun, nítorí tí kò bá wa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”

50. Jésù sì wí fún un, pé, “Má ṣe dá a lẹ́kun mọ́: nítorí ẹni tí kò bá lòdì síi yín, ó wà fún yín.”

51. Nígbà tí ọjọ́ àti gbà á sókè ń súnmọ́, ó fi ojú lé ọ̀nà láti lọ sí Jerúsálémù.

52. Ósì rán àwọn ìránṣẹ́ lọ sí iwájú rẹ̀: nígbà tí wọ́n sì lọ wọ́n wọ ìletò kan tí í ṣe ti ará Samaríà láti pèṣè sílẹ̀ dè é.

53. Wọn kò sì gbà á, nítorí ojú rẹ̀ dàbí ẹni pé ó ń lọ sí Jerúsálémù.

54. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Jákọ́bù àti Jòhánù sì rí i, wọ́n ní, “Olúwa wa, jẹ́ kí a pe iná láti ọ̀run wá, kí a sì pa wọ́n run, (bí Èlíjà ti ṣe?)”

55. Ṣùgbọ́n Jésù yípadà, ó sì bá wọn wí, (ó ní, ẹ̀yin kò mọ irú ẹ̀mí tí ń bẹ nínú yín)

56. Nítorí ọmọ ènìyàn kò wá láti pa ẹ̀mí ènìyàn run, bí kò ṣe láti gbà á là. Wọ́n sì lọ sí ìletò mìíràn.

57. Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ọkùnrin kan wí fún un pé, “Olúwa, Èmi ń fẹ́ láti máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”

58. Jésù sì wí fún un pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́; ṣùgbọ́n ọmọ ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.”

59. Ó sì wí fún ẹlòmíràn pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”Ṣùgbọ́n èyí wí fún un pé, “Olúwa, jẹ́ kí èmi lọ sìnkú baba mi ná.”

60. Jésù sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí àwọn òkú máa sìnkú ara wọn: ṣùgbọ́n ìwọ lọ kí o sì máa wàásù ìjọba Ọlọ́run.”

61. Ẹlòmíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, èmi yóò tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ṣùgbọ́n jẹ́ kí n kọ́kọ́ lọ dágbéré fún àwọn ará ilé mi.”

62. Jésù sì wí fún un pé, “Kò sí ẹni, tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun èlò ìtùlẹ̀, tí ó sì wo ẹ̀yìn, tí ó yẹ fún ìjọba Ọlọ́run.”

Ka pipe ipin Lúùkù 9