Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 9:42-57 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

42. Bí ó sì ti ń bọ̀, ẹ̀mí ẹ̀sù náà gbé e ṣánlẹ̀, ó sì nà án tàntàn. Jésù sì bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí, ó sì mú ọmọ náà láradá, ó sì fà á lé baba rẹ̀ lọ́wọ́.

43. Ẹnu sì ya gbogbo wọn sí iṣẹ́ ọláńlá Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nígbà tí hà sì ń ṣe gbogbo wọn sí ohun gbogbo tí Jésù ṣe, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé,

44. “Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wọ̀ yín léti: nítorí a ó fi ọmọ-ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́.”

45. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà kò yé wọn, ó sì ṣú wọn lójú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì mọ̀ ọ́n: ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti bèèrè ìdí ọ̀rọ̀ náà.

46. Iyàn kan sì dìde láàrin wọn, ní ti ẹni tí yóò ṣe olórí nínú wọn.

47. Nígbà tí Jésù sì mọ ìrò ọkàn wọn, ó mú ọmọdé kan, ó gbé e jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀.

48. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọdé yìí nítorí orúkọ mi, ó gbà mí: àti ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi: nítorí ẹni tí ó bá kéré jù nínú gbogbo yín, òun náà ni yóò pọ̀.”

49. Jòhánù sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́, àwá rí ẹnìkan ó ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èsù jáde; àwa sì dá a lẹ́kun, nítorí tí kò bá wa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”

50. Jésù sì wí fún un, pé, “Má ṣe dá a lẹ́kun mọ́: nítorí ẹni tí kò bá lòdì síi yín, ó wà fún yín.”

51. Nígbà tí ọjọ́ àti gbà á sókè ń súnmọ́, ó fi ojú lé ọ̀nà láti lọ sí Jerúsálémù.

52. Ósì rán àwọn ìránṣẹ́ lọ sí iwájú rẹ̀: nígbà tí wọ́n sì lọ wọ́n wọ ìletò kan tí í ṣe ti ará Samaríà láti pèṣè sílẹ̀ dè é.

53. Wọn kò sì gbà á, nítorí ojú rẹ̀ dàbí ẹni pé ó ń lọ sí Jerúsálémù.

54. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Jákọ́bù àti Jòhánù sì rí i, wọ́n ní, “Olúwa wa, jẹ́ kí a pe iná láti ọ̀run wá, kí a sì pa wọ́n run, (bí Èlíjà ti ṣe?)”

55. Ṣùgbọ́n Jésù yípadà, ó sì bá wọn wí, (ó ní, ẹ̀yin kò mọ irú ẹ̀mí tí ń bẹ nínú yín)

56. Nítorí ọmọ ènìyàn kò wá láti pa ẹ̀mí ènìyàn run, bí kò ṣe láti gbà á là. Wọ́n sì lọ sí ìletò mìíràn.

57. Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ọkùnrin kan wí fún un pé, “Olúwa, Èmi ń fẹ́ láti máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”

Ka pipe ipin Lúùkù 9