Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 9:36-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

36. Nígbà tí ohùn náà sì dákẹ́, Jésù nìkan ṣoṣo ni a rí. Wọ́n sì pa á mọ́, wọn kò sì sọ ohunkóhun tí wọ́n rí fún ẹnikẹ́ni ní ọjọ́ wọ̀nyí.

37. Ó sì ṣe, ní ijọ́ kejì, nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti orí òkè, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn wá pàdé rẹ̀.

38. Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan nínú ìjọ kígbe sókè, pé “Olùkọ́ mo bẹ̀ ọ́, wo ọmọ mi: nítorí ọmọ mi kan ṣoṣo náà ni.

39. Sì kíyèsí i, ẹ̀mí ẹ̀sù a máa mú un, a sì máa kígbe lójijì; a sì máa nà án tàntàn títí yóò fi yọ ìfófòó lẹ́nu, a máa pa á lára, kì í tilẹ̀ ń fẹ́ fi í sílẹ̀ lọ.

40. Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ láti lé e jáde: wọn kò sì lè ṣe é.”

41. Jésù sì dáhùn pé, “Ìran aláìgbàgbọ́ àti àrékérekè, èmi ó ti bá yín gbé pẹ́ tó? Èmi yóò sì ti ṣe sùúrù fún yín pẹ́ tó? Fa ọmọ rẹ wá níhín-ín yìí.”

42. Bí ó sì ti ń bọ̀, ẹ̀mí ẹ̀sù náà gbé e ṣánlẹ̀, ó sì nà án tàntàn. Jésù sì bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí, ó sì mú ọmọ náà láradá, ó sì fà á lé baba rẹ̀ lọ́wọ́.

43. Ẹnu sì ya gbogbo wọn sí iṣẹ́ ọláńlá Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nígbà tí hà sì ń ṣe gbogbo wọn sí ohun gbogbo tí Jésù ṣe, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé,

44. “Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wọ̀ yín léti: nítorí a ó fi ọmọ-ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́.”

45. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà kò yé wọn, ó sì ṣú wọn lójú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì mọ̀ ọ́n: ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti bèèrè ìdí ọ̀rọ̀ náà.

46. Iyàn kan sì dìde láàrin wọn, ní ti ẹni tí yóò ṣe olórí nínú wọn.

Ka pipe ipin Lúùkù 9