Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 9:10-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Nígbà tí àwọn àpósítélì sì padà dé, wọ́n ròyìn ohun gbogbo fún un tí wọ́n ti ṣe. Ó sì mú wọn, ó sì lọ sí apákan níbi ijù sí ìlú tí a ń pè ní Bẹtiṣáídà.

11. Nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn sì mọ̀, wọ́n tẹ̀lé e: ó sì gbà wọ́n, ó sì sọ̀rọ̀ ìjọba Ọlọ́run fún wọn; àwọn tí ó fẹ́ ìmúláradá, ni ó sì mú láradá.

12. Nígbà tí ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ sí rẹlẹ̀, àwọn méjìlá wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Tú ìjọ ènìyàn ká, kí wọn lè lọ sí ìletò àti sí ìlú yíká, kí wọn lè wò, àti kí wọn lè wá oúnjẹ: níbi ijù ni àwa sá wà níhín-ín.”

13. Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Ẹ fi oúnjẹ fún wọn jẹ!”Wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò ní ju ìṣù àkàrà márùn-un lọ, pẹ̀lú ẹja méjì: bí kò ṣe pé àwa lọ ra oúnjẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí.”

14. Nítorí àwọn ọkùnrin náà tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn, ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Kí wọ́n mú wọn jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́, ní àràádọ́ta.”

15. Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì mú gbogbo wọn jókòó.

16. Nígbà náà ni ó mú ìṣù àkàrà márùn-un, àti ẹja méjì náà, nígbà tí ó gbé ojú sókè, ó súre sí i, ó sì bù ú, ó sì fifún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, kí wọn gbé e kalẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn.

17. Wọ́n sì jẹ, gbogbo wọn sì yó: wọ́n ṣa apẹ̀rẹ̀ méjìlá jọ nínú àjẹkù tí ó kù fún wọn.

18. Ó sì ṣe, nígbà tí ó ku òun nìkan ó gbàdúrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀: ó sì bi wọ́n pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi èmi pè?”

19. Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Jòhánù Onítẹ̀bọmi; ṣùgbọ́n ẹlòmíràn ní Èlíjà ni; àti àwọn ẹlòmíràn wí pé, ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ni ó jíǹde.”

20. Ó sì bi wọ́n pé, “Ṣùgbọ́n tani ẹ̀yin ń fi èmi pè?”Pétérù sì dáhùn, wí pe, “Kírísítì ti Ọlọ́run.”

21. Ó sì kìlọ̀ fún wọn, ó sì pàṣẹ fún wọn, pé, kí wọn má ṣe sọ èyí fún ẹnìkan.

Ka pipe ipin Lúùkù 9