Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 8:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ó sì ṣe lẹ́yìn náà, tí ó ń lá gbogbo ìlú àti ìletò kọjá lọ, ó ń wàásù, ó ń ròyìn ayọ̀ ìjọba Ọlọ́run: àwọn méjìlá sì ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀,

2. Àti àwọn obìnrin kan, tí a ti mú láradá kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí búburú àti nínú àìlera wọn, Màríà tí a ń pè ní Magidalénè, lára ẹni tí ẹ̀mí èṣù méje ti jáde kúrò.

3. Àti Jòánà aya Kúsà tí í ṣe ìríjú Hẹ́rọ́dù, àti Ṣùsánà, àti àwọn púpọ̀ mìíràn, tí wọ́n ń ṣe ìránṣẹ́ fún un nínú ohun ìní wọn.

4. Nígbà tí ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn pé jọ pọ̀, àwọn ènìyàn láti ìlú gbogbo sì tọ̀ ọ́ wá, ó fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé:

5. “Afúrúgbìn kan jáde lọ láti fún irúgbìn rẹ̀: bí ó sì ti ń fúrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, a sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ṣà á jẹ.

6. Òmíràn sì bọ́ sórí àpáta; bí ó sì ti hù jáde, ó gbẹ nítorí tí kò ní ìrinlẹ̀ omi.

7. Òmíràn sì bọ́ sínú ẹ̀gún; ẹ̀gún sì dàgbà pẹ̀lú rẹ̀ sókè, ó sì fún un pa.

8. Òmíràn sì bọ́ sí ilẹ̀ rere, ó sì hù sókè, ó sì so èso ọrọrún.”Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí tán, ó náhùn sókè pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́!”

9. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi í léèrè, pé, “Kí ni a lè mọ òwe yìí sí?”

Ka pipe ipin Lúùkù 8