Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 7:31-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Olúwa sì wí pé, “Kí ni èmi ìbá fi àwọn ènìyàn ìran yìí wé? Kí ni wọ́n sì jọ?

32. Wọ́n dàbí àwọn ọmọ kékeré tí ó jókòó ní ibi ọjà, tí wọ́n sì ń kọ sí ara wọn, tí wọ́n sì ń wí pé“ ‘Àwa fọn fèrè fún yín,ẹ̀yin kò jó àwa sì ṣọ̀fọ̀ fún yín,ẹ̀yin kò sọkún!’

33. Nítorí Jòhánù Onítẹ̀bọmi wá, kò jẹ àkàrà, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu ọtí-wáìnì; ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù?’

34. Ọmọ ènìyàn dé, ó ń jẹ, ó sì ń mu; ẹ̀yin sì wí pé, ‘Wò ó, Ọ̀jẹun, àti ọ̀mùtí, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn “ẹlẹ́sẹ̀!” ’

35. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀ gbogbo dá a nipa ọgbọ́n tí ó lò.”

36. Farisí kan sì rọ̀ ọ́ kí ó wá bá òun jẹun, ó sì wọ ilé Farisí náà lọ ó sì jókòó láti jẹun.

37. Sì kíyèsí i, obìnrin kan wà ní ìlú náà, ẹni tí i ṣe ẹlẹ́sẹ̀, nígbà tí ó mọ̀ pé Jésù jókòó, ó ń jẹun ní ilé Farisí, ó mú ṣágo kekeré alabásítà òróró ìkunra wá,

38. Ó sì dúró tì í lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn, ó ń sọkún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i fi omijé wẹ̀ ẹ́ ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ nù ún nù, ó sì ń fi ẹnu kò ó ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi òróró kùn wọ́n.

39. Nígbà tí Farisí tí ó pè é sì rí i, ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Ọkùnrin yìí ìbá ṣe wòlíì, ìbá mọ ẹni àti irú ẹni tí obìnrin yìí jẹ́ tí ń fi ọwọ́ kàn an, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”

40. Jésù sì dáhùn, ó wí fún un pé, “Símónì, Mo ní ohun kan sọ fún ọ.”Ó sì dáhùn pé, “Olùkọ́ máa wí.”

41. “Ayánilówó kan wà tí ó ní ajigbésè méjì: ọ̀kan jẹ ẹ́ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta owó idẹ, èkejì sì jẹ ẹ́ ní àádọ́ta.

Ka pipe ipin Lúùkù 7