Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 7:20-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé, “Jòhánù Onítẹ̀bọmi rán wa sọ́dọ̀ rẹ, pé, ‘Ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?’ ”

21. Ní wákàtí náà, ó sì ṣe ìmúláradá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nínú àìsàn, àti àrùn, àti ẹ̀mí búburú; ó sì fi ìríran fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn afọ́jú.

22. Jésù sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹ padà lọ, ẹ ròyìn nǹkan tí ẹ̀yín rí, tí ẹ̀yín sì gbọ́ fún Jòhánù: àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúkún-ún rìn, a sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn, a ń jí àwọn òkú dìde, àti fún àwọn òtòsì ni à ń wàásù ìyìn rere.

23. Alábùkún fún sì ni ẹnikẹ́ni tí kò kọsẹ̀ lára mi.”

24. Nígbà tí àwọn oníṣẹ Jòhánù padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ síí sọ fún ìjọ ènìyàn ní ti Jòhánù pé, “Kí ni ẹ̀yin jáde lọ sí ijù lọ wò? Iféfèé tí afẹ́fẹ́ ń mì?

25. Ṣùgbọ́n kínni ẹ̀yin jáde lọ wò? Ọkùnrin tí a wọ̀ ní aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́? Wò ó, àwọn tí á wọ̀ ní aṣọ ògo, tí wọ́n sì ń jayé, ń bẹ ní ààfin ọba!

26. Ṣùgbọ́n kíni ẹ̀yin jáde lọ wò? Wòlíì? Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ó sì ju wòlíì lọ!

27. Èyí yìí ni ẹni tí a ti kọ̀wé nítorí rẹ̀ pé:“ ‘Wò ó, mo rán oníṣẹ́ mi ṣíwájú rẹ;ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe níwájú rẹ.’

28. Mo wí fún yín nínú àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí wòlíì tí ó pọju Jòhánù Onítẹ̀bọmi lọ: ṣùgbọ́n ẹni tí ó kéré jùlọ ní ìjọba Ọlọ́run, ó pọ̀ jù ú lọ.”

29. (Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó gbọ́ àti àwọn agbowó òde, wọ́n dá Ọlọ́run láre, nítorí tí a fi ìtẹ̀bọmi Jòhánù tẹ̀ wọn bọ mi.

30. Ṣùgbọ́n àwọn Farisí àti àwọn amòfin kọ ète Ọlọ́run fún ara wọn, a kò bamitísí wọn lọ́dọ̀ rẹ̀.)

31. Olúwa sì wí pé, “Kí ni èmi ìbá fi àwọn ènìyàn ìran yìí wé? Kí ni wọ́n sì jọ?

32. Wọ́n dàbí àwọn ọmọ kékeré tí ó jókòó ní ibi ọjà, tí wọ́n sì ń kọ sí ara wọn, tí wọ́n sì ń wí pé“ ‘Àwa fọn fèrè fún yín,ẹ̀yin kò jó àwa sì ṣọ̀fọ̀ fún yín,ẹ̀yin kò sọkún!’

33. Nítorí Jòhánù Onítẹ̀bọmi wá, kò jẹ àkàrà, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu ọtí-wáìnì; ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù?’

Ka pipe ipin Lúùkù 7