Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 7:2-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ọmọ ọ̀dọ̀ balógun ọ̀rún kan, tí ó ṣọ̀wọ́n fún un, ṣàìsàn, ó sì ń kú lọ.

3. Nígbà tí ó sì gbúròó Jésù, ó rán àwọn àgbààgbà Júù sí i, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wá mú ọmọ ọ̀dọ̀ òun láradá.

4. Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Jésù, wọ́n fi ìtara bẹ̀ ẹ́, pé, “Ó yẹ ní ẹni tí òun ìbá ṣe èyí fún:

5. Nítorí tí ó fẹ́ràn orílẹ̀ èdè wa, ó sì ti kọ́ sínágọ́gù kan fún wa.”

6. Jésù sì ń bá wọn lọ.Nígbà tí kò sì jìn sí etí ilé mọ́, balógun ọ̀rún náà rán àwọn ọ̀rẹ́ sí i, pé, “Olúwa, má ṣe yọ ara rẹ lẹ́nu: nítorí tí èmi kò yẹ tí ìwọ ìbá fi wọ abẹ́ òrùlé mi:

7. Nítorí náà èmi kò sì rò pé èmi náà yẹ láti tọ̀ ọ́ wá: ṣùgbọ́n sọ ní gbólóhùn kan, a ó sì mú ọmọ-ọ̀dọ̀ mi láradá.

8. Nítorí èmi náà pẹ̀lú jẹ́ ẹni tí a fi sí abẹ́ àṣẹ, tí ó ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi, mo sì wí fún ọ̀kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ; àti fún òmíràn pé, ‘Wá,’ a sì wá; àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.”

9. Nígbà tí Jésù gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu sì yà á sí i, ó sì yípadà sí ìjọ ènìyàn tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó wí pé, “Mo wí fún yín pé èmi kò rí irú ìgbàgbọ́ ńlá bí èyí nínú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì.”

10. Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ sì padà sí ilé, wọ́n bá ọmọ-ọ̀dọ̀ náà tí ń sàìsàn, ara rẹ̀ ti dá

11. Ní ijọ́ kejì, ó lọ sí ìlú kan tí a ń pè ní Náínì: àwọn púpọ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń bá a lọ àti ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn.

12. Bí ó sì ti súnmọ́ ẹnu ibodè ìlú náà, sì kíyèsí i, wọ́n ń gbé òkú ọkùnrin kan jáde, ọmọ kan ṣoṣo náà tí ìyá rẹ̀ bí, ó sì jẹ́ opó: ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ìlú náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀.

13. Nígbà tí Olúwa sì rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó sì wí fún un pé, “Má sọkún mọ́.”

14. Ó sì wá, ó sì fi ọwọ́ tọ́ àga pósí náà: àwọn tí ń rù ú dúró jẹ́. Ó sì wí pé, “Ọ̀dọ́mọkùnrin, mo wí fún ọ, dìde!”

Ka pipe ipin Lúùkù 7