Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 4:23-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Jésù sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó pa òwé yìí sí mi pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ̀ sàn! Àwọn ohun tí àwá gbọ́ pé o ti ọwọ́ rẹ ṣe ní Kapanáúmù, ṣe é níhín yìí pẹ̀lú ní ilẹ̀ ara rẹ.’ ”

24. Ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, kò sí wòlíì tí a tẹ́wọ́ gbà ní ilẹ̀ baba rẹ̀.

25. Ṣùgbọ́n mo wí fún un yín nítòótọ́, opó pípọ̀ ni ó wà ní Ísírẹ́lì nígbà tí ọ̀run fi sé ní ọdún mẹ́ta òun oṣù mẹ́fà, nígbà tí ìyàn ńlá fi mú ká ilẹ̀ gbogbo;

26. Kò sì sí ẹnìkan nínú wọn tí a rán Èlíjà sí, bí kò ṣe sí obìnrin opó kan ní Sáréfátì, ìlú kan ní Ṣídónì.

27. Adẹ́tẹ̀ púpọ̀ ní sì ń bẹ ní Ísírẹ́lì nígbà wòlíì Èlíṣà; kò sì sí ọ̀kan nínú wọn tí a wẹ̀nùmọ́, bí kò ṣe Námánì ará Síríà.”

28. Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó wà nínú sínágọ́gù gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, inú wọ́n ru ṣùṣù,

29. Wọ́n sì dìde, wọ́n tì í sóde sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n sì fà á lọ sí bèbè òkè níbi tí wọ́n gbé tẹ ìlú wọn dó, kí wọn bá à lè taari rẹ̀ ní ògèdèǹgbé.

30. Ṣùgbọ́n ó kọjá láàrin wọn, ó bá tirẹ̀ lọ.

31. Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Kápánáúmù, ìlú kan ní Gálílì, ó sì ń kọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi.

32. Ẹnu sì yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀: nítorí tàsẹtàṣẹ ni ọ̀rọ̀ rẹ̀.

33. Ọkùnrin kan sì wà nínú Sínágọ́gù, ẹni tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, ó kígbe ní ohùn rara,

34. “Ó ní, kíní ṣe tàwa tìrẹ, Jésù ará Násárẹ́tì? Ìwọ́ wá láti pa wá run bí? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe; Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.”

35. Jésù sì bá a wí gidigidi, ó ní, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí o sì jáde lára rẹ̀.” Nígbà tí ẹ̀mí èṣù náà sì gbé e ṣánlẹ̀ ní àwùjọ, ó jáde kúrò lára rẹ̀, kò sì pa á lára.

36. Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ wí pé, “ẹ̀kọ́ kínni èyi? Nítorí pẹ̀lú àṣẹ àti agbára ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí àìmọ́ wí, wọ́n sì jáde kúrò.”

37. Òkìkí rẹ̀ sì kàn níbi gbogbo ní agbégbé ilẹ̀ náà yíká.

38. Nígbà tí ó sì dìde kúrò nínú sínágọ́gù, ó sì wọ̀ ilé Símónì lọ; ibà sì ti dá ìyá ìyàwó Símónì gúnlẹ̀; wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ nítorí rẹ̀.

Ka pipe ipin Lúùkù 4