Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 4:2-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ogójì ọjọ́ ni a fi dán an wò lọ́wọ́ Èṣù. Kò sì jẹ ohunkóhun ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì: nígbà tí wọ́n sì parí, lẹ́yìn náà ni ebi wá ń pa á.

3. Èṣù sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ fún òkúta yìí kí ó di àkàrà.”

4. Jésù sì dáhùn, ó wí fún un pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípa àkàrà nìkan.’ ”

Ka pipe ipin Lúùkù 4